Minimum Wage: Alága òṣìṣẹ́ Ekiti ní òǹyẹ̀ kò leè yẹ sísan ₦30,000 owó oṣù

Alága ẹgbẹ́ òṣìsẹ́ ìpínlẹ̀ Ekiti, Kolapọ Olatunde ti kéde pé ,ìjọba àpapọ yóò san ẹgbẹ̀rún lọna ọgbọn náírà owó oṣù òṣìsẹ́ tó kére jùlọ losù kẹ́sàn ọdún yìí.

Olatunde sàlàyé èyí nílu Ado -Ekiti, lásikò tó fi n dá àwọn àkọroyin lójú pé, kò sí ǹkan tó le yẹ aigbowó osù fáwọ́n òṣìṣẹ́ nínú ọ̀ṣẹ̀ àkọ́kọ́ nínú òṣù tọ ń bọ̀ yìí.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O fí kún pé àwọn atúnṣe kan to yọjú tí ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ ń gbíyànjú láti ṣe àtúnto rẹ, ló fa ìdádúró sísàn owó náà.

Alaga ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ tún sàlàyé pé, atunyàn Chris Ngige sípò mínísítà fún ọ̀rọ̀ òṣìṣẹ́, jẹ́ kó mú ọ̀rọ̀ owó òṣìṣẹ́ ni òkúnkúndùn láti rii pe ó di sísàn.

Ọ̀pọ̀ ìgbà ní ìjọba àti àwọn olórí òṣìsẹ́ ti jà túka lái fẹ́nu ọ̀rọ̀ jọ́nà lórí owó òṣìsẹ́ tó kére jùlọ.