Osun Supreme: Àwọn èèyàn Ọṣun rọ Oyetọla láti jẹ́ kí àsìkò rẹ̀ tú aráàlú lára

Àkọlé fídíò, Osun Supreme: Àwọn èèyàn Ọṣun rọ Oyetọla láti jẹ́ kí àsìkò rẹ̀ tú aráàlú lára

Lẹyin idajọ ileẹjọ to ga julọ nilẹ wa pe, gomina ipinlẹ Ọṣun, Adegboyega Oyetọla ni ojulowo gomina fun ipinlẹ naa, BBC Yoruba fẹsẹ kan de ilu Ẹdẹ ati Osogbo lati gbọ ero awọn araalu nipa isẹlẹ naa.

Ọpọ awọn eeyan to ba wa sọrọ nilu Ẹdẹ lo rọ gomina Oyetọla, lati mase fi oju alatako ati alaida wo awọn eeyan ilu Ẹdẹ.

Bakan naa ni wọn rọ gomina, lati se atunse awọn opopona to wa nilu ọhun ti ọpọ wọn ti dẹnu kọlẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Awọn eeyan ipinlẹ Ọsun tun panupọ parọwa si gomina Oyetọla, lati jẹ ki igba rẹ tu awọn lara, ko ma si jẹ awọn osisẹ ọba lowo osu wọn.