You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Emir Sulu Gambari kú ara fẹ́rakù
Iya Emir ti ilu Ilorin, Alhaji Sulu Gambari, Alhaja Aishat Nma Sulukarnaini ti re ibi agba n re.
Gẹgẹ bi iroyin to jade lati aafin Emir, o ti ṣe diẹ ti Mama Nma ti n ba aisan ọjọ ogbo fa a ko to wa di pe o jẹ Ọlọhun nipe ni ile iwosan Fasiti Ilorin.
Lẹyin ti wọn kirun Ishai tan lalẹ ọjọ aje oṣu kẹfa ọdun 2019 ni Mama Nma jade laye.
Iya Emir Sulu Gambari ni ọmọ ọmọ Emir ikeeje to jẹ ni ilu Ilorin, ọmọ Emir ikẹjọ, to fi wa jẹ iyawo Emir ikẹsan, oloogbe Alhaji Sulu Karnaini Gambari.
Awọn eekan lorilẹede Naijiria ati ni ilu Ilorin ti n fi ikini ranṣẹ si Emir Sulu Gambari.
Mama Nma tun jẹ aburo si Emir ikẹwaa to jẹ ni Ilorin ati iya to bi Emir to wa lori oye bayii, Alhaji Ibrahim Sulu-Gambari CFR.
Ẹni ọdun marunlelọgọrun ni mama yii nigba to pade ọlọjọ.