You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Eid-Al-Fitr: ìjọba Nàìjíríà ti kéde ìsinmi lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun àti Ọjọ́rú
Ile iṣe ijọba apapọ to n risi ọrọ abẹle Naijiria kede isinmi fawọn eniyan.
Wọn kede pe ko ni si iṣẹ ni ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kẹrin, oṣu yii ati ni ọjọ karun un, Ọjọru ọsẹ yii.
Georgina Ehuriah to jẹ akọwe agba ajọ naa lo kede isinmi yii lorukọ ijọba apapọ.
Bakan naa ni akọwe agba yii parọwa fawọn ẹlẹsin Islam pe ki wọn ma yọ ayọ ti ko yẹ lasiko yii.
O ni ki wọn lepa ifẹ, alaafia àti iṣokan fun ogo Naijiria lapapọ.
Ehuriah sọrọ lori ifarada ki idagbasoke le de ba Naijiria lasiko iṣejọba aarẹ Buhari tuntun yii.
Aawẹ Ramadan jẹ ọkan lara opo marun un ẹsin Islam.
Ehuriah parọwa pé ki wọn sa fun ọrọ ikorira ki wọn si fọwọsowọpọ pẹlu aarẹ Buhari ninu iṣejọba tuntunt yii.
Ile iṣẹ ijọba apapọ yii tun paṣẹ pe ki awọn oṣ\iṣẹ eleto aabo Naijiria fọwọsowọpọ ṣiṣẹ papọ lasiko ọdun itunnu aawẹ yii.