Ọwọ́ tẹ ọkunrìn tó n fi kẹ́míkà ṣe ìtọ́jú àìsàn jẹjẹrẹ àti ibà.

Oríṣun àwòrán, AFP
Ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ti tẹ ọkunrin ọmọ orilẹ-ede Britain kan, to n pin kẹmika to n yọ idọti 'bleach' fun awọn eniyan gẹgẹ bi omi iyanu.
Ọwọ ọlọpaa orilẹ-ede Uganda tẹ Sam Little, ati ọmọ orilẹ-ede Uganda meji: Sauel Albert, ati Samula Tadeop ni Ọjọbọ niluu Fort Portal lorilẹ-ede naa.
Wọn fi ẹsun kan awọn ọkunrin mẹtẹẹta ọhun pe wọn fun awọn ọmọ orilẹ-ede Uganda kan ni kẹmika ti wọn ṣe latara 'Chlorine Dioxide'.
Kẹmika yii jẹ eyi ti awọn ileeṣẹ fi n yọ idọti ninu eyi to hande pe wọn pe e fun wọn ni Omi iṣẹ iyanu, ti wọn si ni o n wo aisan bi i jẹjẹrẹ ati ibà san lara.
Ọgbẹni Little ti sọ ọ ri pe oun n ran awọn ọmọ Uganda lọwọ nipa pipese iwosan olowo pọọku fun wọn.
Sugbọn, ko ti i sọ ohunkohun lati igba ti awọn ọlọpaa ti mu u.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe wọn ba igbó ati omi iyanu naa nile rẹ.
Wọn ti fi ofin de omi iyanu naa ni ọpọlọpọ orilẹ-ede, wọn si ni o n fa eebi, ati aisan inu ẹjẹ.
Ileeṣẹ ọlọpaa ti kesi awọn to ti gba omi iyanu naa lati yọju sita fun ẹrí.
















