You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Champions league: Àwọn ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù wo ni yóò tẹ̀síwájú?
Tani yoo tẹsiwaju lọ si ipele olójú mẹ́jọ (Quarter finals) idije Champions league ilẹ Yuroopu lọṣẹ yii?
Ibeere yii ni yoo maa gba ọkan awọn ololufẹ ere bọọlu kaakiri agbaye bi ifẹsẹwọnsẹ to kẹyin ni ipele komẹsẹ-o-yọ akọkọ ni Champions league yoo ṣe waye lọjọ iṣẹgun ati ọjọru.
Borussia Dortmund vs Tottenham
Ẹgbẹ agbabọọlu Borussia Dortmund ti orilẹede Germany yoo maa gbalejo Tottenham hotspur ti ilẹ Gẹẹsi ni orilẹede Germany.
Goolu mẹta ni Tottenham gba wọle Borussia Dortmund nigba ti wọn pade ni ọsẹ meji sẹyin ni papa iṣire Wembley.
Real Madrid vs Ajax.
Igba mẹta ọtọọtọ ni Real Madrid ti gba ife ẹyẹ Champions league laarin ọdun mẹrin sẹyin. Awọn si ni ikọ agbabọọlu akọkọ ti yoo gba ife ẹyẹ naa ni ọdun mẹta tẹleri.
Madrid yoo maa gbalejọ Ajax lọjọ iṣẹgun lẹyin ti wọn ti kọkọ rinrinajo lọ si orilẹede Holland ni ọsẹ meji sẹyin nibi ti wọn ti po ẹkọ iya fun Ajax nilu Amsterdam pẹlu ayo meji si ẹyọkan.
Ṣe Madrid ni yoo tẹsiwaju ni tabi Ajax, ipade di papa iṣire Barnebaeu ni orilẹede Spain.
FC Porto vs Roma
Ni ọjọru ni FC Porto orilẹede Portugal yoo gbalejo Roma ti ilẹ Italy. Nigba ti wọn pade ni ọsẹ meji sẹyin ni ilu Romu, ami ayo meji si ẹyọkan ni Roma fi na FC Porto.
Ireti ọpọ si ni pe boya Porto yoo lo anfani ọdẹdẹ rẹ to wa lati yii oju ọrọ pada ki wọn lee tẹsiwaju.
Paris Saint Germain PSG vs Manchester United
Anọmọle ni PSG na Manchester United mọ old Trafford nigba ti ikọ mejeeji yii pade ni old Trafford ni ilẹ Gẹẹsi.
Lootọ awọn agbabọọlu Man United n ta biọbiọ lẹnu lọọlọọ yii ni idije liigi premiership ilẹ naa ṣugbọn ọpọ n woye pe agbara wọn yoo ku diẹ lati ka PSG, paapaa julọ bo ṣe jẹ pe ojude PSG lorilẹede France ni ifẹsẹwọnsẹ naa yoo ti waye.
Pẹlu awọn ifẹsẹwọnsẹ mẹrin yii lọsẹ yii awọn ololufẹ bọọlu yoo mọ awọn mẹrin akọkọ ti yoo lọ si ipele to kan ni idije Champions league.