Nigeria 2019 Elections: Ta ni Sani tó ń ṣe PVC fún INEC, tó tún ńdupò sẹ́nétọ̀?

Sani Musa

Oríṣun àwòrán, Sani Musa 313/Facebook

Lọjọ Abamẹta ni ẹgbẹ oṣelu alatako nipasẹ Osita Chidoka to ṣoju alaga ẹgbẹ oṣelu Peoples democratic Party, PDP nibi ipade ijiroro ti aj INEC n ṣe pẹlu awọn eekan ilu nilu Abuja lẹyin ti wọn kede isunsiwaju eto idibo, fi ẹsun kan pe ileeṣẹ to n pese kaadi oludibo fun INEC jẹ ti ọkan lara ọmọ ẹgbẹ All Progressives Congress, APC, to tun n dije fun ipo sẹnetọ ni ẹkun idibo ila oorun ipinlẹ Niger.

Iroyin fidirẹmulẹ pe ọdun 2011 ni ileeṣẹ naa labẹ orukọ Act Technologies Limited ti n gba iṣẹ agbaṣe lọwọ ajọ INEC, ati pe ohun lo pese awọn ẹrọ ti INEC fi tẹ kaadi oludibo fun eto idibo ọdun 2015.

Ẹgbẹ oṣelu PDP n fẹsun kan pe 'ko yẹ ki ọkunrin naa, nipa alakalẹ ọmọluabi, jẹ ki ileeṣẹ rẹ gba iṣẹ agbaṣe naa lati ṣe kaadi oludibo ninu eto idibo ti oun funra rẹ ti n kopa.

Ati pe kini idi ti INEC tun fi gbe iṣẹ agbaṣe lati tẹ kaadi oludibo fun eto idibo 2019 t'oun funra rẹ ti n kopa gẹgẹ bi oludije?

Nigba ti wọn fi ẹsun naa kan, alaga ajọ INEC, Mahmood Yakubu fesi pe lootọ ni ajọ ti n ṣiṣẹ pẹlu ileeṣẹ naa lati ọdun 2011 , Activate Technologies Limited, amọ 'ko ni ṣe idiwọ fun eto idibo ti ko ni mago-mago ninu.''

Ati wi pe oṣiṣẹ INEC kankan ko ni i gbabọde.

Kini a mọ nipa ọkunrin naa?

Iwadi wa lori ayelujara fihan pe Mohammed Sani Musa di ẹni to ni ileeṣẹ Activate Technologies Limited ninu oṣu Kini, ọdun 2012. Ileeṣẹ naa maa n ṣe awọn nkan to wulo fun imọ ijinlẹ ibaraẹnisọrọ (ICT).

O jẹ oludamọran pataki fun ijọba ipinlẹ Niger laarin ọdun 2008 si 2011.

Ileeṣẹ rẹ, Activate Technologies Limited to maa n ṣe awọn kaadi ẹrọ ayarabiaṣa maa n gba iṣẹ agbaṣe lọwọ awọn ileeṣẹ ijọba Naijiria bii:

  • Ajọ INEC
  • Ajọ to n ṣe kaadi idanimọ orilẹede Naijiria, NIMC
  • Ileeṣẹ Ọlọpaa
  • Ileeṣẹ ijọba apapọ to wa fun ọrọ abẹle
  • Ajọ to n mojuro awọn fasiti Naijiria, NUC
  • Ijọba ipinlẹ Niger
  • Ijọba ipinlẹ Kaduna, ati
  • Ijọba ibilẹ Adamawa