NigeriaDecides2019: Àwọn èèyàn Ekó figbe ta pé ìṣúnsíwájú ìbò ṣàkóbá fáwọn

Àkọlé fídíò, NigeriaDecides2019: Bi ìṣúnsíwájú ìbò tí ṣé s'akoba fún ọrọ ajé wá

Awọn eeyan ilu Eko ti n ba BBC Yoruba sọrọ nipa isunsiwaju ibo ti Inec kede.

Pupọ ninu wọn ti akọroyin wa ba ni gbolohun ladugbo Obalende sọ pe igbesẹ yi ti ṣe akoba fun ọrọ aje wọn.

Pẹlu itara ni wọn fi salaye fun wa pe awọn onibara awọn kọ lati jade latari ikede ti wọn ti gbọ tele pe idibo yoo waye lọjọ abamẹta.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

''Mo ti padanu bi ẹgbẹrun mẹẹdogun Naira loni ti wọn sun idibo si waju'' ni igbe ti arakunrin kan to ni ohun ni ipinu lati dibo.

Jakejado orileede Naijiria ni eto ọrọ aje ti dẹnukọlẹ ti pupọ awọn aaye karakata si da paroparo.