NigeriaDecides2019: Àwọn èèyàn Ìpínlẹ̀ Oyo ní ìṣúnsíwájú ìbò ààrẹ kù díẹ̀ káàtó

Àkọlé fídíò, Àwọn ará Ìpínlẹ̀ Oyo ní ìgbésè INEC lọrí ìdìbò kù díẹ̀ káàtó

Awọn eeyan ipinlẹ Oyo faraya lẹyin ti ajọ eleto idibo Naijiria INEC sun idibo aarẹ ati tile aṣofin agba l'Abuja siwaju, wọn ni igbesẹ naa ko bojumu rara.

Ajọ INEC sọ pe, iṣeto fun idibo ọhun to mẹhẹ lo fa ti awọn fi sun un siwaju, ṣugbọn awọn oludibo nilu Ibadan ni, o yẹ ki bẹẹni ajọ eleto idibo ko maa jẹ bẹẹni.

Diẹ ninu awọn oludibo to ba BBC Yoruba sọrọ lo sọ ẹdun ọkan pe, awọn ko le ri ọja ta mọ nitori ọpọ eeyan ni ko le jade sita mọ, bo tilẹ je pe ajọ INEC ti sun idibo to yẹ ko waye loni siwaju.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: