You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Dino Melaye: Mí ò sí lára àwọn aṣòfin tó bú Buhari
Sẹnetọ to n ṣoju ẹkùn idibo nipinlẹ Kogi, Dino Melaye ti sọ pe oun ko si lara awọn aṣofin to pariwo le Aarẹ Muhammadu Buhari lori lasiko to n ka aba eto iṣuna ọdun 2019 niwaju awọn aṣofin Naijiria lọjọ kọkandinlogun, oṣu Kejila, ọdun 2019.
Melaye to n bẹ nileewosan gbogboogbo l'Abuja lọwọlọwọ, sọ ninu atẹjade kan ti oluranlọwọ rẹ, Gideon Ayọdele, fi sita pe irọ ni ẹsun ti awọn kan fi n kan oun pe awọn jọ bu Aarẹ Buhari.
Melaye sọ pe ''ko ṣeesẹ ki oun wa lara awọn aṣofin tó pariwo ẹlẹya le Buhari lori, nitpri pe oun ko si nibi eto ti Buhari ti gbe aba eto iṣuna naa kalẹ.
Ati wi pe kii ṣe ẹ̀rù lo mu ki oun ṣọ pe oun ko jẹbi ẹsun naa, ati pe ki ẹnikẹni to ba ni ẹri pe oun ba wọn kopa ninu rẹ jáde wa sọ.