You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
INEC Amina Zakari: Mi ò tan mọ́ ààrẹ Buhari rárá o!
Amina Zakari ti ọpọ eniyan ati paapaa julọ ẹgbẹ oṣelu alatako PDP ni awọn lodi si iyansipo rẹ ni ajọ eleto idibo INEC ti fesi.
Akọroyin BBC kan si i lojukoroju, o si baa ni gbolohun ninu eyi ti Amina Zakari ti sọ wi pe "Mi o kii ṣe ọmọ ẹgbọn tabi aburo aarẹ.
Labẹ iṣejọba aarẹ ana, Gooduck Jonathan ni wọn ti yan mi sipo ... mo si ti ṣiṣẹ fún ọpọlọpọ aarẹ Naijiria mii".
O fi kun un wi pe ojuṣe oun ko tilẹ̀ tan mọ ohun ti àwn to n pariwo n ro rara. "Ojuṣe mi ni lati rii daju pe ibudo kika wa ni ipo to dara fun ohun ti yoo waye nibẹ".
"Alaga ajọ eleto lo ni ojuṣe ati ka gbogbo abajade esi idibo loju gbogbo eniyan".
Iyansipo Amina Zakari gẹgẹ bi olori igbimọ ibudo ikabo aarẹ ti yoo waye loṣu keji ọdun 2019 ni ọpọ paapaa ẹgbẹ oṣelu PDP bẹrẹ si ni sọ pe ko tọ pẹlu oniruuru idi.
Lara rẹ ni wi pe ibatan aarẹ Muhammadu Buhari lo jẹ ko si boju mu ko wa nidi ibo kika ninu idibo kan naa ti mọlẹbi rẹ ti jẹ oludije.