You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
NASS: Gbogbo àwọn ǹkan tó mú ìṣúnà ọdún 2019 yàtọ̀ #Budget2019
Ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàijíríà, Muhammadu Buhari lásìkò tó gbé àbá ìṣúná owó tó tó trílíọ̀nù mẹ́jọ náírà ó lé ọwọ́ mẹ́jọ lọ sí ilé ìgbìmọ aṣòfin lónìí ní àwọn aṣòfín ń kígbe "Sai Baba, Sai Baba"
Buhari sàlàyé àbá ìṣúnà ọdún 2019 níwájú àkójọpọ̀ ilé aṣofin mejéèjì, ní bi ti ọmọ ilé ìgbìmọ̀ aṣójú-sofín àtí sẹnatọ̀ yọ́wọ́ ẹ̀sẹ́ síra wọ̀n.
Àwọn ọmọ ilé ìgbìmọ asojú-sòfín méjì, Bashir Babale àti Duoye Diri bẹ̀rẹ̀ sí ní ju ẹ̀sẹ́ sí ara wọm lásìkò tí àwọn kan gbé ìwé àkọlé jáde nígba kan bẹ̀rẹ̀ sí ní yaá bí PMNews àti Punch ṣe sọ
Nígbà tí gbogbo ẹ̀nìyàn tí ń ròó pé ǹkan tí rọlẹ̀ ní Sẹnatọ Samuel Anyanwu àti Godwill Akpabio bẹ̀rẹ̀ àríyànjiyàn.
Ìròyìn ti ó tẹ̀ wá lọ́wọ́ ní pé ní ọdún 2015 ti ààrẹ Muhammadu Buhari wá ka àbá ìṣúná owó, kò sí aríyànjiyàn báyìí.
Yakubu Dogara tó jé abẹnugan ilé ìgbìmọ aṣòjú-sòfin àtí ààrẹ ilé ìgbìmọ aṣòfin àgbà Bukola Saraki ló jẹ́ alága tó ń darí abá ìsúnà, bákan náà ló ń ka àwọn aṣeyorí nínú abá ìṣúna tí ọdún 2018 ní àwọn ọmọ ilé ìgbìmọ ẹgbẹ́ keji bẹ̀rl síní pariwo lé wọn lóri
Àbá ìṣúná ti ọdún yìí tí ààrẹ pé ni ìsúná ipele tó kàn kò pọ̀ tó èyí to pada fọ́wa sí lọ́dún 2018.
kíní àwọn àwọn ènìyàn ń sọ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ tó wáyé nílé ìgbìmọ̀ aṣofin