MMA: ilé Epo Forte oil gbiná súkẹ́rẹ́-fàkẹrẹ ọkọ̀ ti bẹ̀rẹ̀

Oríṣun àwòrán, LASEMA
Ilé epo Forte Oil tó wà ní abáwole pápákọ̀ òfurufú Muritala Muhammed tó wà ní Ikẹ̀ja ló dédé gbaná lọ́sàn òní.
Lásìkò tí ìròyìn yìí tẹ̀ wá lọ́wọ́ ohun tó fa iná ọ̀hún kò sí ẹni tó lè sọ, bótilẹ̀ jẹ́ pé àwọn panápaná tí ṣe akìtiyan bí wọn o ṣe paá.
Agbenusọ ilé iṣẹ́ panápaná ìpínlẹ̀ Eko Amodu Shaikiru tó bá BBC sọ̀rọ̀ sàlàyé pé àwọn ò ti le fídi ohun to fa ina náà múlẹ̀ sùgbọn àwọn sì ń gbìyànjú láti pána báyìí.

Oríṣun àwòrán, LASEMA
Ọ̀kan nínú àwọn òṣìṣẹ́ pápákọ̀ òfurufú náà sàlàyé pé ìjàmbá náà kò bá burú jáì bíkò ṣe ìgbéṣẹ̀ àwọn pánápána tó wà ní pápákọ̀ òfurufú.
'' Àwọn òṣìṣẹ́ FAAN ló kọ́kọ́ jígìrì sí iṣẹ́ náà láàrín ìṣẹ́jú mẹ́jọ tó bẹ̀rẹ̀ tí wọn sì gbìyànjú láti ma jẹ kí ó ràn mọ àwọn ilé míràn tó wà ní àyíká.
ìròyìn tó tẹ BBC lọ́wọ́ fi yé ni pé súkẹrẹ fàkẹrẹ ọkọ̀ tí gbàlú kan láwọn agbègbè tó gba ọ̀nà náà kọjá













