Diezani: Iléẹjọ́ ní Diezani yẹ kó sọ tẹnu rẹ̀ lórí ẹ̀sùn àjẹbánu lẹ́ka èpò rọ̀bì

Oríṣun àwòrán, @diezanimadueke
Ileeẹjọ giga tilu Abuja ti pasẹ lọjọ isẹgun pe ki ajọ EFCC lọ gbe minisita fọrọ epo rọbi ni isejọba to kọja, Diezani Allison Madueke, ẹni ti wọn n tanna wadi rẹ lọwọ ni ilu Ọba.
Adele Agbẹnusọ fun ajọ EFCC, Tony Orilade lo sisọ loju ọrọ yii fawọn akọroyin.
Iroyin naa ni adajọ to n gbọ ẹjọ ti EFCC gbe wa nipa ẹsun ajẹbanu ti wọn fi kan Diezani, Valentine Ashi, pasẹ fun EFCC, ileesẹ ọlọpaa, ileesẹ ọtẹlẹmuyẹ atawọn ileesẹ agbofinro yoku lati wa Diezani lawari ti obinrin n wa nkan ọbẹ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Adajọ Ashi fikun pe awọn ileesẹ naa gbọdọ di Diezani lapa n yaka wa siwaju oun laarin ọjọ mẹta pere ti oun gbe asẹ naa kalẹ.









