Ibura Gomina: Akọ̀wé ìjọba àpapọ̀ ló sojú Buhari

Oríṣun àwòrán, Gbemi Jesuleke
Alhaji Gboyega Oyetọla ni wọn ti bura fun gẹgẹ bii gomina tuntun ni ipinlẹ Ọsun.
Adajọ agba nipinlẹ naa, Oyebọla Adepele lo dari eto ibura fun gomina Oyetọla ati igbakeji rẹ ni deede aago mejila aabọ ọsan.
Nigba to n sọrọ nibi ayẹyẹ naa, Asaaju fun ẹgbẹ APC ni Naijiria , Bola Ahmed Tinubu kọrin re ki Gomina to n fipo silẹ ni ipinlẹ Ọsun, Rauf Arẹgbẹsọla
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Orin ibilẹ ilẹ wa si ni wn fi side ayẹyẹ naa
Lara awọn eeyan pataki ti o tun darapọ mọ ipejọpọ naa ni Ọọni Ile Ifẹ, Ọba Enitan Ogunwusi, Ọjaja keji, Alaafin Ọyọ, Ọba Lamidi Adeyẹmi .

Oríṣun àwòrán, @Oyetola_Gboyega
Awọn ọba alaye yoku ni Ataọja ilu Ọṣogbo, adari ẹgbẹ oṣelu APC, Bọla Tinubu ati aya rẹ, Senatọ Olurẹmi Tinubu ati gomina ipinlẹ Ọṣun tẹlẹri, Oloye Adebisi Akande ati bẹẹbẹẹ lọ.

Awọn gomina ipinlẹ Ekiti, Ọndo, Ọyọ, Eko, Kogi ati Kano naa ko gbẹyin nibi ayẹyẹ ibura naa.
Adajọ agba ipinlẹ Ọṣun, arabinrin Adepele Ojo naa ti wa ni kalẹ lati ṣe akoso iburawọle ọhun.
Akọwe ijọba apapọ orilẹede yii, Boss Mustapha lo ṣoju aarẹ Muhammadu Buhari nibi ipejọpọ naa.

Oríṣun àwòrán, Omonijo Sunday
Bakan naa, ọgọọrọ awọn oṣiṣẹ ijọba, ọniṣe ọwọ, ọniṣowo, agunbanirọ ati awọn aṣoju ijọba ipinlẹ Ọṣun lo pejupesẹ si papa iṣere gbilu Ọṣogbo fun ayẹyẹ naa.
Awọn ladelade-loyeloye naa ko gbẹyin ninu awọn to wa ba gomina tuntun yọ. Lara awọn Ọba alade to ti wa nikalẹ ni Ọrangun Ile Ila ati Oluwo ti Ilu Iwo.

Oríṣun àwòrán, Omonijo Sunday
Lati aago mẹwa owurọ lo ti yẹ ki eto naa gbinaya, sugbọn titi di asiko yii, a ṣi n reti gomina tuntun, igbimọ alakoso ẹgbẹ oṣelu APC ati awọn alejo pataki mii nibi ayẹyẹ naa.
Alẹ ana ni awọn alejo pataki ti n wọle si ilu Osogbo fun ayẹyẹ ibura naa, lara awọn to kọkọ de ni asaaju ẹgbẹ oselu APC ni Naijiria, Bọla Ahmed Tinubu.
INEC kede ajáwé olúborí nípìnlẹ Ọṣun
Ajọ eleto idibo lorilẹede Naijiria ti bẹrẹ kika esi idibo si ipo gomina ni ipinlẹ Osun.
Adari INEC ni ẹkun Guusu-Iwọ Oorun orilẹede Naijiria, Ọmọọba Deji Soyebi ati awọn adari Ajo INEC ni ipinlẹ Osun, Rivers, Ebonyi, Cross Rivers, Nasarawa, Gombe, Sokoto, Kano, Edo, Benue lo peju pese si ibẹ.
Adari Ajọ Inec ni Osun, Olusegun Agbaje dupẹ lọwọ gbogbo awọn to jẹ ki eto idibo naa lọ ni irọwọrọsẹ lai si rogbodiyan ninu.
O fi kun un wi pe ẹgbẹ oselu mejidinlaadọta lo dije dupo gomina ni ipinlẹ naa.

Ọjọ kejìlélógún, oṣù kẹsan an, ọdún 2018 ni àwọn èèyàn ìpínlẹ Ọṣun dìbò yan ẹni tó wù wọ́n sìpó gomina fún saa ọdún mẹrin tó m bọ.
Ṣùgbọn abajade náà kò ṣẹnu 're fún awọn ara Ọṣun gẹ́gẹ́ bí àjọ INEC ṣe kéde wí pé
Bi o tilẹ jẹ pe eto idibo gomina nipinlẹ Ọsun naa lọ ni irọwọ-rọsẹ, sibẹ a gbọ lati ẹnu oludari eto idibo ni ijọba ibilẹ Orolu pe, agọ idibo mẹta ni wọn ti ja apoti idibo gba, ti wọn ko si wọgile ibo lawọn agọ idibo mẹtẹtẹta naa.
Ni bayii, awon egbe oselu ti bere si ni ka esi idibo fun woodu ati unit won.
Esi idibo lati awọn ijọba ibilẹ ni ipinlẹ Osun
Boluwaduro APC 3,843PDP 3779
Atakumosa west
APC 5019PDP 5401
Ifedayo LGA
APC 3182PDP 3374
Ede South
APC 4512PDP 16693
Orolu LG
APC 5442PDP 7776
Obokun LGA
APC 7229PDP 10859
IleṣaEast
APC 9790PDP 8244
Boripe
APC 11655PDP 6892
Ilesa West
APC 7251PDP 8286
Oriade
APC 9778PDP 10109
Irẹpodun
APC 6517PDP 8058
Ila
APC 8403PDP 8241
Iṣọkan
APC 7297PDP 9048
Odo Ọtin
APC 9996PDP 9879
Ayedade
APC 10861PDP 9836
Atakumọsa East
APC 7073PDP 5218
Ẹdẹ North
APC 7025PDP 18745
Ifẹlodun
APC 9882PDP 12269
Ayedire
APC 5474PDP 5133
Ifẹ North
APC 6527PDP 5486
Ejigbo
APC 14779PDP 11116
Ẹgbẹdọrẹ
APC 7354PDP 7231
Ifẹ Central
APC 6957PDP 3200
Irewọle
APC 10049PDP 13848
Ọlọrunda
APC 16254PDP 9850
Ọlaoluwa
APC 5025PDP 4026
Ifẹ́ South
APC 7223PDP 4872
Ifẹ East
APC 8925PDP 6608
Iwo
APC - 7644PDP - 6122
Oṣogbo
APC - 23379PDP - 14499














