Ìbúra Gómìnà: Tinubu, Oluwo àtàwọn èèkànlú míì ló péjú síbi ìbúra Oyetọla

Se ni aṣọ n pe aṣọ ransẹ nibi ayẹyẹ ibura fun gomina tuntun nipinlẹ Ọsun, Alhaji Gboyega Oyetọla lọjọ Isẹgun.

Remi Tinubu atawọn obinrin miran

Oríṣun àwòrán, @Oyetola_Gboyega

Àkọlé àwòrán, Sẹnetọ Olurẹmi Tinubu atawọn obinrin miran toju wọn gun rege ko gbẹyin nibi ayẹyẹ ibura naa
Awọn obinrin to wọ asọ ẹgbẹjọda

Oríṣun àwòrán, @Oyetọla_Gboyega

Àkọlé àwòrán, Ayẹyẹ ti awọn obinrin arẹwa ko ba peju si, ode naa ko lee dun. Awọn amodedun ree nikalẹ
Oloye Remi Tinubu n rin lọsibi ijoko atawọn alejo miran

Oríṣun àwòrán, @Oyetọla_Gboyega

Àkọlé àwòrán, Ẹsẹ ko gbero pẹlu ọpọ alejo nilu Osogbo
Bola Tinubu n ki obinrin kan to di mọ

Oríṣun àwòrán, Omominjo Sunday

Àkọlé àwòrán, Ayẹyẹ ibura ku ọla ni Oloye Bọla Tinubu de silu Osogbo fun ayẹyẹ ibura naa
Awọn eeyan to wọ asọ ẹgbẹjọda
Àkọlé àwòrán, Se ni asọ ẹgbẹjọda n pe asọ ẹgbẹjọda ransẹ nilu Osogbo
Oluwo ati Ọba miran joko ti awọn eeyan kan
Àkọlé àwòrán, Awọn Oriade ati ọrun ilẹkẹ joko wa wa wa sibi ayẹyẹ ibura naa, ninu wọn la ti ri Oluwo tilu Iwo
Awọn eeyan to wọ asọ ẹgbẹjọda
Àkọlé àwòrán, Awọn oloye atawọn ọtọkulu ilu n duro ki ayẹyẹ naa bẹrẹ
Awọn eeyan to peju sibi ayẹyẹ ibura
Àkọlé àwòrán, Gbagede ibura kun fun ọpọ ero nilu Osogbo
Oluwo ati Ọba kan
Àkọlé àwòrán, Oluwo ati Ọba kan fi ijoko wọn yẹ gomina tuntun si
Awọn ọdọ
Àkọlé àwòrán, Awọn obitibiti ọdọ ko see ka nibi ayẹyẹ ibura naa
Oloye Bisi Akande atawọn miran lọ pade Bola Tinubu

Oríṣun àwòrán, Omominjo Sunday

Àkọlé àwòrán, Lara awọn alejo to kọkọ de silu Osogbo nigba ti ọjọ ayẹyẹ ku ọla, ni asaaju ẹgbẹ oselu APC ni Naijiria, Bọla Ahmed Tinubu.
Awọn obinrin meji n ba Tinubu sọrọ
Àkọlé àwòrán, Asaaju ogun ti kii kẹyin ogun ree nibi ayẹyẹ ree