Toriọla: ó yẹ kí a jẹ́ káwọn ọmọ ìsinyi mọ pàtàkì ṣíṣe eré ìdánilárayá papọ̀
Eré ìdárayá lè mú ìṣọ̀kan tó ti sọnù ní Nàìjíríà padà ti gbogbo òbí àti alágbàtọ̀ ba n da ọmọ pọ tọ́ láì ṣe ẹlẹ́yàmẹ̀yà.
Ikọ BBC ba Tọpẹ Toriọla àti Sandra ọmọ Ìgbò ti wọn jọ n ṣere idanilaraya àtijọ́, iyẹn Tẹn-Tẹn sọrọ.
O mẹnuba bi òun ṣe dagba ni ariwa Akurẹ nipinlẹ Ondo nibiti àwọn akẹgbẹ oun ni kilaasi wa lati ẹ̀yà oriṣiiriṣii.
Loju tirẹ, ìṣokan maa n wa laarin awọn èwe ti wọn ba jọ n ṣere idanilaraya pọ̀ ni.
Eré idanilaraya maa n jẹ ki ọmọde ni ifarada, ìfẹ́ àti ìṣọkan ni nitori wọn á ri ara wọn gẹgẹ bii ọ̀rẹ́.
Ọmọ ti ayé ba bi ni ayé ń pọ̀n, bi gbogbo òbí ba ṣe n fún àwọn ọmọ laaye lati ṣe ere idanilaraya papọ naa ni ki à maa kiyesi iwà àti ìṣe wọn.