Adegoke: APC kò tẹ̀lé ìlànà ìdìbò tó yẹ l'Ọ́ṣun

Amofin Kunle Adegoke to jẹ ọkan lara awọn oludije fun gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC ni ipinlẹ Ọṣun ninu idibo abẹnu APC, to kọja ti gba ile ẹjọ giga apapọ̀ ni ilu Abuja lọ, pẹlu ẹbẹ pe ki ile ẹjọ o wọgile esi idibo abẹnu ẹgbẹ oselu naa to waye.
Ẹgbẹ oṣelu APC, ati ajọ eleto idibo INEC ni amofin naa gbe lọ siwaju ileẹjọ lori ọrọ naa.
Ninu iwe ipẹjọ rẹ, Adegoke n rọ ile ẹjọ lati kede rẹ pe idibo naa ko ba ilana ti igbimọ amuṣẹya APC la kalẹ, ti igbimọ alakoso rẹ si tun fọwọ si mu.
Ibo to le dẹ ni ẹgbẹrun mẹtadinlaadoje (127,017) ni Oyetọla ni, nigba ti Amofin Kunle Adegoke ni ibo ọtalelugba o din mẹjọ, 252.
Ọgbẹni Gboyega Oyetọla lo gbegba oroke nibi idibo abẹle ẹgbẹ oṣelu APC to waye ni ogunjọ Oṣu Keje.

O ni ki ile ẹjọ wọgile idibo naa nitori ko gbe ilana ati eto to yẹ ni titẹle kalẹ fun idibo naa.
Adegoke wa beere fun aṣẹ ile ẹjọ eleyi ti yoo ka ẹgbẹ oṣelu APC lapako lati maṣe lo esi idibo abẹnu naa lati fi kopa ninu eto idibo sipo gomina ti yoo waye nipinlẹ Ọṣun, lọjọ kejilelogun Oṣu Kẹsan.









