Etò ààbò ìdìbò abẹ́lé APC Ekiti kúrò ní kèrémí lòní

Asia APC

Oríṣun àwòrán, @apcnigeria

Àkọlé àwòrán, Lálá yóò lù loni, APC Ekiti yóò yan olùdíje gómìnà wọn

Gomina Al Makura, tó ń ṣètò ìdìbò Ekiti ni kélé a gbé ẹni tó bá fẹ́ da ìdìbò tòní rú

Àwọn ọmọ ìgbìmọ̀ tó ń ṣeto idibo abẹle fun ẹgbẹ oṣelu APC ni ipinlẹ̀ Ekiti ti fi àwọn ènìyàn lókàn balẹ pé yoo yọri si rere loni.

Gomina ipinlẹ Nassarawa to jẹ alaga igbimọ, Gomina Al Makura, naa ni ki gbogbo àwọn oludibo wa pẹlu àmì ìdánimọ̀ tó ba òfin mu ki wọn tó le wọle.

Igbimọ naa ni wọn ti fi òfin de àwọn to da idibo rú lọsẹ to kọja àti pe ìjìyà to tọ́ ń duro de àwọn ti adé òfin ba ṣimọ lori ninu wọn.

Amin iyasọtọ kan

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò, Aborisade: Mẹ̀kúnù gbọ́dọ̀ funra sí Obasanjo

Wón ni ẹnikẹni kò gbọdò wọ aṣọ to ń polongo oludije kankan loni.

Awọn kan gba pe ti idibo abẹle yii kò bá ti waye, o di dandan ki ẹgbẹ fa oludije kan kalẹ̀ ni eyi ti àwọn kò fẹ́.

Bayii, ọpọlọpọ àwọn agbofinro lo ti wa ni Ekiti lati rii pé ohun gbogbo lọ ni irọworọsẹ.