APC: Ìdìbò abẹ́lé Èkìtì yóò wáyé lọ́jọ́ kọkànlá oṣù Karùn-ùn

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress, APC, ti dá ọjọ́ mìi fún ètò ìdìbò abẹ́lé sí ipò gómìnà tó foríṣánpọ́n ní ìpínlẹ̀ Èkìtì.
Ètò ìdìbò nàá yóò wáyé báyìí lọ́jọ́ kọkànlá, oṣù Karùn ún ọdún 2018.
Akọ̀wé ìpolongo fún ẹgbẹ́ nàá, Bolaji Abdullahi, fi ìkéde nàá síta nígbà tó n bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ lólú ilé ẹgbẹ́ APC tó wà ní ìlú Abuja.
Ìgbìmọ̀ tó ń se agbátẹrù ètò ìdìbò nàá, gbé àbọ̀ ìwádìí tó ṣe lórí ètò ìdìbò tó forísánpọ́n lọ́jọ́ Àbámẹ́ta nítorí rògbòdìyàn, kalẹ̀ lọ́jọ́ Ajé.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Ẹgbẹ́ nàá ti ṣèlérí láti ṣe àtúngbéyẹ̀wò ìṣẹ̀lẹ̀ nàá.
Àwọn olùdíje mẹ́tàlélọ́gbọ̀n, ló n jà fita-fita láti gba tíkẹ́ẹ̀tì ẹgbẹ́ APC. Lára wọn la ti rí àwọn gómìnà nígbà kan rí, àti àwọn aṣòfin àgbà mẹ́ta nígbàkan rí.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Àmọ́, ìròyìn tó n tó wa lọ́wọ́ sọ pé, asaájú kan fẹgbẹ́ òṣèlú APC, Aṣíwájú Bọla Tinubu, gómínà tẹ́lẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Ògùn, Àrẹ̀mọ Ṣẹgun Ọ̀ṣọbà, àti àwọn àṣàyàn èèyàn nínú ẹgbẹ́ nàá n ṣe ìpàdé ìdákọ́nkọ́ lọ́wọ́ nílé ìjọba ìpínlẹ̀ Èkó tó wà ní Abuja.
Ìpàdé nàá ni, ìwé ìròyìn Punch sọ pé ó dá lórii àti fẹnukò lórí ọ̀nà àbáyọ sí ètò ìdìbò tó dàrú l'Ékìtì.












