Ọlọ́pàá Èkó gbé ẹni tó pa ìyàwó àti ọmọ rẹ̀ re'lé ẹjọ́

Ami ileese olopa orilẹede Naijiria

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, ọlọ́pàá gbé ẹni tó pa ìyàwó àti ọmọ rẹ̀ re'lé ẹjọ́

Ile isẹ ọlọpa ni ipinlẹ Eko sọ wipe ọmọkunrin kan lati orilẹede Denmark, Peter Nielsen ti wọn fẹsun kan wipe o pa iyawo ati ọmọ rẹ ni awọn yoo gbe rele ẹjọ ni Ọjọru.

Agbẹnusọ fun ile isẹ ọlọpa naa, Chike Otti sọ wipe ẹni ti wọn fẹsun kan yoo kawọ pọnyin rojọ ni ile ẹjọ to wa ni Yaba, ni ilu Eko.

Otti wipe Kọmisona fun awọn ọlọpa, Imohimi Edgar ti paṣẹ fun ile iṣẹ ọlọpaa lati gbe ọkunrin naa lọ si ile ẹjọ nitori iwadi ti awọn ọlọpaa ṣe ati ayẹwo ti awọn dokita ṣe fun awọn oloogbe naa.

Gẹgẹbi ọrọ awọn ọlọpaa, iyawo to d'oloogbe naa, Alizee ati ọmọ rẹ to jẹ ọmọ ọdun mẹrin ni wọn ba oku wọn ninu ile wọn to wa ni Banana Island, ni ilu Eko pẹlu amin lilu ni ara wọn.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: