Iléeṣẹ́ ológun Nàìjíríà: Irọ́ ni sájẹ́ńtì David Bako pa

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Iléeṣẹ́ ológun oríilẹ̀ lórílẹ̀èdè Nàìjíríà, ti ṣàlàyé wí pé, kò sí òótọ́ nínú ọ̀rọ̀ kan tí arákùnrin kan tó pe ara rẹ̀ ní Sájẹ́ńtì David Bako, tó ní òun ti sá kúrò lẹ́nu iṣẹ́ ológun ń sọ kiri lórí ayélujára wí pé, àbámọdá ni ìṣẹ̀lẹ̀ ìjínigbé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Dapchi tó wáyé, àti pe, ilé áárẹ, Aso rock villa, ni wọ́n ti parí ìlànà láti ṣe iṣẹ́ náà fún ọgọ́rin mílíọ̀nù náírà.
Nínú àtẹ̀jáde kan tó fi síta, agbẹnusọ fún iléeṣẹ́ ológun oríilẹ̀ lórílẹ̀èdè Nàìjíríà, Ọ̀gágun Texas Chukwu ni, iléeṣẹ́ ológun oríilẹ̀ kò mọ ohunkóhun nípa àhesọ ọ̀rọ̀ tí arákùnrin náà ń gbé káàkiri, àti pé, kí àwọn ọmọ orílẹ̀èdè Nàìjíríà kọ etí ikún sí ọ̀rọ̀ náà.

Awọn iroyin ti ẹ lee nifẹẹ si:

Iléeṣẹ́ ológun wá fi kún un wí pé, lẹ́yìn àyẹ̀wò ìwé àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀, kò sí èyíkéyí nínú ọmọogun oríilẹ̀ lórílẹ̀èdè Nàìjíríà, yálà àwọn tó wà lẹ́nu isẹ́ lọ́wọ́lọ́wọ́ ni tàbí àwọn tó sá lọ kúrò lẹ́nu isẹ́, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ David Bako.
Iléesẹ́ ológun ní òun kò lọ́wọ́ òsèlù
Iléeṣẹ́ ológun oríilẹ̀ lórílẹ̀èdè Nàìjíríà wá tẹnumẹ́ ìdúróṣinṣin rẹ̀ láì gbè sẹ́yìn igun òṣèlú kankan, bẹ́ẹ̀ni ó ní òun kò báwọn lọ́wọ́ nínú òṣèlú bí ó ti wulẹ̀ kó mọ.
Bákan náà ló tún sọọ síwájú síi wí pé, gbogbo àwọn gbọ́ọ̀yísọ̀yí tí wọ́n ń sọ ohun tí kò ṣẹlẹ̀ káàkiri, ni wọ́n yóò fi jófin láìpẹ́.









