NUJ: A fẹ mọ ẹsẹ awọn akọroyin tẹ da duro

Oríṣun àwòrán, @AIT_Online
Ileesẹ BBC ti fidi rẹ mulẹ pe ileesẹ agbohunsafẹfẹ AIT ati ileesẹ itẹwe iroyin The Sun ti juwe ọna ile fawọn osisẹ rẹ to le ni ọọdunrun niye.
Gẹgẹbi di lara awọn osisẹ ti isẹlẹ naa kan, amọ ti wọn fẹ ka fi orukọ bo wọn ni asiri ti wi, se fidi rẹ mulẹ, ọjọ ẹti ni wọn pin iwe maa rele rẹ naa fun awọn, lai mọ idi to fi ri bẹẹ.
Biotilẹpe ẹnikan ninu wọn ni, iwe ifẹyinti ni wọn pe iwe idaduro naa amọ wọn ko fi idi rẹ mulẹ boya ileesẹ mejeeji sọwedowo mọ iwe maa lọ sile rẹ naa.
Nigba to nba ileesẹ BBC sọrọ lori isẹlẹ yi, Aarẹ ẹgbẹ akọroyin ni Naijiria, Waheed Odusile gbọnmu lori bi ileesẹ agbohunsafẹfẹ AIT ati ileesẹ itẹwe iroyin The Sun se juwe ọna ile fawọn osisẹ toto ọọdunrun niye.
Odusile ni ẹgbẹ akọroyin yoo tanna wadi isẹlẹ naa lati mọ ohun tawọn ileesẹ ọhun ri lọbẹ, ti wọn se waaru ọwọ.
O fikun pe ti iwadi naa ba fihan pe wọn kan fẹ fi iya jẹ awọn akọroyin naa lọna aitọ ni, ẹgbẹ NUJ yoo faraya si isẹlẹ yi.
O wa rọ awọn ileesẹ AIT ati The Sun lati san gbogbo ẹtọ awọn akọroyin ti wọn da duro naa, eyiun to ba jẹ pe bi wọn se gba isẹ lọwọ wọn ba ofin mu.

Awọn iroyin ti ẹ lee nifẹẹ si:

Bakannaa ni aarẹ ẹgbẹ akọroyin lorilẹede yi kaanu pe kii se isẹlẹ to dara rara ki awọn eeyan maa padanu isẹ wọn lasiko yi ti ọrọ aje Naijiria ko rẹrin rara.
Odusile tun rawọ ẹbẹ sawọn ileesẹ iroyin to ba jẹ awọn akọroyin lowo osu lati tete san owo naa nitori oogun alaaru ko gbọdọ gbẹ.













