'Ileesẹ ọmọogun Naijiria ko mọ nipa awọn ọmọ ti wọn tu silẹ'

Ileesẹ ologun lorilẹede Naijiria ko lee sọ boya wọn ti ri eyikeyi ninu awọn ọmọbinrin ileewe girama Government Girls Secondary School, ni ilu Dapchi, ipinlẹ Yobe ti awọn agbebọn kọlu.
Gẹgẹbi ọrọ to sọ fun ileeṣẹ BBC, agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọmọogun lorilẹede Naijiria, Ọgagun John Agim ni gomina ipinlẹ Yobe lo lee sọrọ lẹkunrẹrẹ lori awọn ọmọ ti wọn ri gba pada.
Ọgagun John Agim ni ileeṣẹ ọmọogun ko tii lee sọ boya lootọ ni wọn ji awọn ọmọ ileewe naa gbe tabi wọn kan sa f'arapamọ ni.
"A ko mọ iye awọn ọmọ ileewe to wa ni ileewe ti a n sọ ọrọ rẹ yii. A ko si mọ, ni pato iye ọmọ ti wọn ji gbe.
"Mi o si lee sọ pẹlu idaniloju iye awọn ọmọ ti wọn ti da silẹ. O di igba ti isẹ akanṣe ti awọn ọmọogun n ṣe nibẹ baa pari ni a to lee ni iroyin to kun rẹrẹ. Iṣẹ si n lọ nibẹ."

Oríṣun àwòrán, Getty AFP
Bakanna, agbẹnusọ fun aarẹ orilẹede Naijiria, Garba Shehu ti fi idi rẹ mulẹ wi pe Aarẹ Buhari ti ran awọn minisita mẹta, eyi ti minisita fun eto abo, Mansur Mohammed Dan-Ali lewaju, lọ si ipinlẹ Yobe loojọ ọjọọbọ lati lọ se iwadi lori ikọlu alẹ ọjọ aje nibi ti awọn agbebọn ikọ agbesunmọmi Boko Haram ti ji awọn ọmọ ileewe kan ko nibẹ.
Ileesẹ aarẹ orilẹede Naijiria ni bi o tilẹ jẹ wipe iroyin jade pe wọn ti ri lara awọn ọmọ naa, sibẹ ohun ti awọn eeyan n sọ nipe wọn si n wa lara awọn ọmọ ileewe naa.
Bakannaa ni aarẹ Buhari tun ti dari awọn ologun ati ọlọpa lọ si agbegbe naa lẹyẹ-o-sọka ki wọn si se awari awọn ọmọ ileewe to sọnu naa.












