Akala burial: Òní ní Oloye Christopher Adebayo Alao Akala yóò wọ káà ilẹ̀ lọ ní Ogbomoṣo

Oloogbe Alao Akala wọ kaa ilẹ lọ ni ilu Ogbomoso.

Opolopo awọn eekan ni Naijiria lo peju pesẹ sibi eto isinki gomina ipinlẹ Oyo nigba kan ri, Oloye Christopher Adebayo Alao Akala.Wo àwọn ǹkan tó yẹ kí o mọ̀ nípa Alao Akala tó dágbére fáyé lẹ́ni ọdún 71

Nibẹ naa ni gbogbo ero ati ẹbi ati ara ati iyekan oloogbe ti wa ṣe ẹyẹ ikẹyin fun un ni ilu abinibi rẹ ni Ogbomoso ni ipinlẹ Oyo to wa ni Iwo oorun guusu Naijiria.

Oni, ọjọ kejidinlogun, oṣu keji, ọdun 2021 ni wọn yoo sin ara Alao Akala ni Ogbomoso.

Oloye Christopher Adebayo Alao Akala to ti tukọ ipinlẹ Oyo ri doloogbe ni aarọ kutu ọjọ Ru, ọjọ kejila, oṣu kinni, ọdun 2022.

Ile rẹ to wa ni ilu rẹrr ni Ogbomoso ni ipinlẹ Oyo ni Guusu Iwo oorun Naijiria ni ọlọjọ ti wa mu Akala lọ.

Ta ni Alao Akala ti wọn n sin loni?

Ọjọ Kẹta, Osu Kẹfa, ọdun 1950 ni wọn bi gbajugbaja oloselu, Christopher Adebayo Alao-Akala.

Alao-Akala lọ si ile iwe Government Technical College, Tamale, Ghana ati Ogbomoso High School, Ogbomoso.

Nigba to pari nibẹ, o tẹsiwaju lọ si ile iwe giga fasiti ti ilu Ibadan.

Lẹyin naa lo bẹrẹ isẹ ọlọpaa titi to fi gba oye ADC si Ọga Agba Ọlọpaa lorilẹede Naijiria.