Olubadan: Seyi Makinde ní àwọn aláìmọ́kan kọ́ ni yóò kọ́ òun bí òun yóò ṣe tọjú àwọn arúgbó bíi Olubadan

Gomina ipinlẹ Ọyọ, Onimọ ẹrọ Ṣeyi Makinde ti sọrọ lori awuyewuye to rọ mọ igbesẹ fifi Olubadan miran jẹ.

Gomina Makinde lo ṣe abẹwo si mọlẹbi Olubadan to waja, Ọba Saliu Akanmu Adetunji, Aje Ogunguniso Kinni, ni aafin rẹ to n bẹ ni Popo Yemọja nilu Ibadan.

Makinde, lasiko abẹwo naa wa kede pe eto isinku to larinrin yoo waye fun Ọba alade naa pẹlu afikun pe ilana bi a ṣe n jẹ Olubadan ti ilẹ Ibadan gbọdọ pada si bi o ṣe wa tẹlẹri.

Atẹjade kan ti akọroyin fun gomina ipinlẹ Ọyọ, Taiwo Adisa fisita fawọn akọroyin tọka si pe gomina ni "eleyii ni yoo jẹ igba ikẹyin ti awuyewuye yoo rọ mọ ẹni ti o kan lati gun ori itẹ Olubadan ti ilẹ Ibadan".

O wa fi da gbogbo ọmọ ati ololufẹ ilẹ Ibadan loju wi pe ijọba oun yoo tẹsiwaju ninu igbagbọ ninu ohun ti itẹ Olubadan duro fun.

O fi alaye kun pe, oun yoo sa gbogbo ipa lati mu ọla ati iyi ba ilana bi a ṣe n jẹ Olubadan ti ilẹ Ibadan.

Nigba to n sọrọ lori ariwisi awọn eeyan kan to fi ẹsun kan wi pe o yẹ ki gomina pada sile lati irinajo rẹ lọgan to gbọ iroyin nipa ipapoda Olubadan ti ilẹ Ibadan.

Makinde wa fesi wi pe, "Lonii, mo duro ni iwaju gbogbo eniyan lati sọ wi pe awọn to ni o yẹ ki n pada wale lọgan ti mo gbọ iroyin ipapoda Baba ko ni imọ. Bẹẹni.''

''Gbogbo igba ni mo n ba Baba sọrọ. Mo wa ni ilu Ṣaki nigba ti wọn ṣaisan, mo si n ba awọn Dokita to n tọju wọn nile iwosan sọrọ".

"Nitori naa, awọn to n yọ ẹnu si ọrọ kọ ni yoo kọ wa bi o ti yẹ ki a tọju awọn arugbo wa. Mo wa lati sọ fun un yin pe gbogbo wa ni ipapoda Baba dun".

Ninu ọrọ ti ẹ, ọmọ Olubadan ana, Ọmọwe Abdul Raheem Adetunji dupẹ lọwọ gomina ati awọn to kọwọrin pẹlu rẹ fun abẹwo ibanikẹdun naa, o si gbadura pe ki Ọlọrun mu wọn ṣe aṣeyọri ni gbogbo ọna.