Kidnapping on Lagos-Ibadan express: Àwọn 33 afurasí ajínigbé tó ń ṣọṣẹ́ ní òpópónà Eko sí Ibadan ti wà ní àhàmọ́ àjọ ọlọ́pàá

Àjọ ọlọ́pàá ti nawọ́ gán àwọn afurasí gẹ́gẹ́ bí ajínigbé mẹ́tàlélọ́gbọ̀n tó jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ oríṣìíríṣìí tán ń jí àwọn arìnrìnàjò gbé ní òpópónà márosẹ̀ Eko sí Ibadan. Ọlọ́pàá Oyo bẹ̀rẹ̀ kán lu ìgbó láti wá àwọn ajínigbé lópópónà Lagos-Ibadan Expressway

Àwọn afurasí ọ̀hún, tí àjọ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Oyo nawọ́ gán, jẹ́ èyí tí àwọn afurasí ajínigbé tó ń ṣọṣẹ́ ní agbègbè Onigari níbi òpópónà márosẹ̀ náà níbi tí wọ́n ti jí àwọn kan tó ń lọ ibi ìgbéyàwó kan gbé láìpẹ́ yìí.

Kọmísọ́nnà àjọ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Oyo, Ngozi Onadeko nígbà tó ń bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ lẹ́yìn tó ṣàfihàn wọn lánàá ní oríkò àjọ ọlọ́pàá tó wà ní Eleyele, Ibadan, ka orúkọ Aliu Umar, Isiaka Ibrahim àti Tambaya Usman lára àwọn tí wọ́n mú.

Onadeko sọ pé àwọn méjìlá nínú àwọn afurasí náà jẹ́ àwọn tó lọ́wọ́ nínú ìjínigbé tó wáyé ní Onigari, ìjọba ìbílẹ̀ Oluyole, lọ́nà márosẹ̀ Eko sí Ibadan.

Bákan náà ló tún ṣàfihàn àwọn afurasí ogún mìíràn fún ẹ̀sùn ìdigunjalè, ìpànìyàn àti ṣíṣe bí ọmọ ogun.

Báwo ni wọ́n ṣe mú àwọn ọ̀daràn náà?

Onadeko ṣàlàyé pé bí ìjínigbé ṣe ń fi gbogbo ìgbà wáyé ní òpópónà márosẹ̀ Eko sí Ibadan àti ìpànìyàn tó wáyé ní Onigari lọ́jọ́ keje, oṣù kìíní mú kí àwọn jí gìrì sí iṣẹ́ ní pẹrẹu.

Ónadeko ní akitiyan àwọn yìí ṣokùnfà kí àwọn nawọ́ gán afurasí kan tó ń jẹ́ Maku-Maku lọ́jọ́ kẹrìnlá, oṣu kìíní, à ti pé nígbà tí àwọn tún tẹ̀síwájú nínú ìwádìí àwọn ni àwọn nawọ́ gan àwọn yòókù.

Ónadeko fi kun un pé àwọn kan ti na pápá bora nínú àwọn afurasí gẹ́gẹ́ bí ọ̀daràn náà.

Onadeko ní àwọn afurasí náà ti jẹ́wọ́ pé àwọn ló wà nídìí ìjínigbé tó wáyé lọ́jọ́ keje, oṣù kìíní ní Onigari níbi tí Oluwatosin Anwajoye, 45, ti pàdánù ẹ̀mí rẹ̀.