You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Yollywood: Odunlade Adekola àti Toyin Abraham tọrọ àforíjìn pé irú èyí kò ní wáyé mọ́
Lọjọ Iṣẹgun ni ọpọ awọn ọmọ Naijiria bọ si ori ayelujara lati sọ ẹdun ọkan wọn lori ilẹ kan ti wọn sanwo ẹ ṣugbon ti wọn ko ri gba.
Wọn tun fẹsun kan awọn gbajugbaja osere ati adẹrinpossonu pe awọn lo ba ileeṣẹ to ta ilẹ naa ti wọn n pe ni 'Revolution Plus'polowo ilẹ ati ile naa ki awọn to ra a.
Ṣé Odunlade Adekola àti Toyin Abraham kò ṣe 'Ambassador' rógo báyìí?
Awọn to n binu lori ayelujara yii ni pe igbagbọ ti awọn ni ninu awọn gbajumọ yii lawọn ṣe lọ sanwo ilẹ naa.
Lara awọn ti wọn n darukọ ni Toyin Abraham, Odunlade Adekola, Broda Shaggi ati Testimony Jaga.
- Àwọn agbébọn pa ọgọ́ta èèyàn ní ibùdó ìfiniwọ̀ ní DR Congo
- Ìjọba Kano fẹ̀sùn oníkókó márùn ún kan àwọn afurasí tó pa ọmọ ọdún márùn ún Hanifa
- Ọdaràn làwọn tó ń pè fún ìdìbò dípò 'Restructuring' tí a n béèrè- Iba Gani Adams OPC
- Mọ̀ sí i nípa Oba Yesufu Asanike, Olubadan tí kìí fi ọ̀rọ̀ sí abẹ́ ahọ́n sọ kódà níwájú sọ́jà
- Oògùn olóró tó lé ní mílíọ̀nù kan la rí gbà lọ́wọ́ àwọn awakọ̀ Onitsha sí Kano- Àjọ NDLEA
- 'Wọ́n gba ọ̀kadà mi, fóònù àti owó, wọ́n tún gba ọwọ́ méjèèjì'
Kini awọn ileeṣẹ ti awọn eeyan fẹsun kan ri sọ si ọrọ to wa nilẹ yii?
Loju opo Instagram Page ileeṣẹ Revolution Plus Property Development Company Ltd lọjọ ru ni wọn ti gbe atẹjade ti wọn sita lori ọrọ ilẹ ati ile naa.
Ileese naa ni pe awọn ti n gbe ariwisi awọn eeyan yẹ wo bayii nitori pe ko si ootọ nibẹ.
Bakan naa ni wọn tun ni pe pẹlu ootọ inu ni won fi gbe ileeṣẹ naa kalẹ.
Ni afikun, Ileeṣẹ naa tun ni pe laipẹ laijinna awọn yoo da gbogbo onibara to n binu si awọn gbajumọ to ba wọn polowo ọja lohun.
Wọn tun yọ orukọ gbogbo awọn to ba wọn polowo ọja ti aye n pariwo wọn kiri kuro ninu ẹbi ọrọ to wa nilẹ yii.
Igbesẹ wo ni toyin Abraham ti gbe lori bi o ṣe jẹ 'Ambassador' ?
Gbajugbaja oju oge Yollywood ti oun naa ba wọn polowo ọja, Toyin Abraham ti ọpọ n pe ni Mama Ire naa ti sọrọ soke lori ọrọ to wa nilẹ yii.
Toyin Abraham bọ si oju opo instagram page rẹ lati ṣalaye bi o ṣe kan an.
Bakan naa ni Toyin Abraham tọrọ aforijin lọwọ gbogbo awọn ti wọn ra ilẹ naa nipasẹ ipolowo ti oun ṣe fun wọn.
O ni gbogbo nkan to ba gba ni oun a fun un ki ohun gbogbo fi tete yanju laipẹ.
O fi da awọn ololufẹ rẹ loju pe ohun gbogbo a yanju nitori olootọ ni wọn.
- U.S. yóò máa fún àwọn ọmo Nàìjíríà kan ní físà ìwé ìrìnnà láì ṣe ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò
- Kìnìún méjì ṣekùpa olùṣọ́gbà ẹranko, wọ́n sì sálọ
- Adájọ́ Munta Abimbola ti da ẹjọ́ tí àwọn Oloye Ibadan tó gba adé lọ́wọ́ Ajimobi nú
- Iná jó oko Obasanjo to wà ní ìpínlẹ Benue, Ẹbọra Òwu bínú, Ortom ni kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ ìwádìí ní kíá
- Tí òògùn owó bá wà nínú Ifa ni, n kò bá ti kọ́ ilé ńlá fún ara mi- Babaláwo
- ASUU Fasiti Obafemi Awolowo fárígá, ìyansẹ́lódì tẹ̀síwájú lórí pínpín owó àjemọ́n;ú àwon Olùkọ́
Kini Odunlade Adekola sọ si ọrọ 'Ambassador' to ṣe di wahala yii?
Odunlade Adekola ti oun naa jẹ ẹni ti igba oju mọ ninu awọn oṣere naa ti sọrọ soke lori iṣẹlẹ naa.
Loju Opo Instagram ti Odunlade Adekola naa lo ti sọrọ.
Adekola naa pada tọrọ aforijin lọwọ awọn ti ọrọ kan.
Saaju ni o ti kọkọ fi ohun lile da a pada fun awọn to n pe e lori iṣẹlẹ naa.
Sugbon bayii, Odunlade ti yi ohun ọrọ rẹ pada pe ki wọn ma binu rara.
Oun naa ni awọn ti n ṣiṣẹ papọ pẹlu ileeṣẹ naa lati tete mu ileri wọn ṣẹ laipẹ laijinna.
Awọn ololufẹ rẹ naa si baa wi loju opo Instagram ẹ pe ko lọ fi kun iwa Omoluwabi rẹ.