Obasanjo farm burnt: Iná jó oko Obasanjo to wà ní Benue, Ẹbọra Òwu bínú, Samuel Ortom ni kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ ìwádìí ní kíá

Oko kan to jẹ ti aarẹ Naijiria tẹlẹ, Olusegun Obasanjo jona.

Ina ti jo oko Orchard Farm to jẹ ti aarẹ tẹlẹ ni Naijiria, Olusegun Obasanjo.

Oko naa to wa ni ilu Howe ni ijọba ibilẹ Gwer nipinlẹ Benue ni iroyin sọ pe o jona ni ọjọ Satide to kọja.

Oko ọhun to to ẹgbẹrun meji ati irínwó le ogún eeka ni Obasanjo gbin orisirisi eso si.

Bo tilẹ jẹ pe ko si ẹni to mọ nkan to fa ina ọhun, iroyin ti a ko ti i fidirẹ mulẹ sọ pe awọn eniyan kan to jẹ ọmọ ìlú lo dana sun nitori pe Obasanjo ko fun wọn ni nkan fun ilẹ wọn.

Kini Akowe Obasanjo so fun BBC Yoruba lori iṣẹlẹ naa?

Akọwe ikede fun Obasanjo, Kehinde Akinyemi sọ fun BBC pe lootọ ni iṣẹlẹ naa waye.

Gẹgẹ bi oludari àjọ paná paná ni ipinlẹ Benue, Donald Ikyaaza, ṣe sọ fun iwe iroyin Punch, o ni awọn osisẹ àjọ naa to lọ lati pa ina ọhun jabọ pe awọn araalu to n binu pe awọn ko ri nkan itunu gba lori ilẹ oko naa lo dana sun.

Olusegun Obasanjo jẹ agbẹ alada nla, to si ni oko kaakiri Naijiria.Ṣugbọn awọn iroyin kan maa n sọ pe ipá lo fi gba awọn ilẹ̀ to n lo fun isẹ agbẹ lasiko to fi jẹ aarẹ ológun ni Naijiria.

Nibo ni ọrọ de duro bayii?

Oloye Olusegun Obasanjọ ti fi aidunnu rẹ han si iṣẹlẹ naa.

Obasanjọ ni oun mọ pe awọn agbofinro ti n ṣiṣẹ iwadii lori iṣẹlẹ naa bi o ti yẹ.

Gomina Samuel Ortom to n tukọ ipinlẹ Benue nitirẹ ti paṣẹ pe ki iwadii bẹrẹ ni kia lori iṣẹle naa ki wọn si fi owo ofin mu awọn ti aje ọrọ naa ba ṣi mọ lori.