Ọba Abdulrasheed Adewale Akanbi: Ààrẹ Muhammadu Buhari yẹ lẹ́ni tó yẹ ká gbé òṣùbà fún lórí àwọn ohun améyérọrùn - Oluwo

Oba Akanbi Teller gboriyin fun Aare Muhammadu Buhari

Oluwo ti Iwo, Ọba Abdulrasheed Adewale Akanbi ti gbóríyìn fún Ààrẹ Muhammadu Buhari fún iṣẹ́ takuntakun tó ń ṣe nídìí ìgbóguntako ìwà àjẹbánu àti ṣíṣe àwọn ohun améyérọrùn ní orílẹ̀ èdè yìí.

Ọba Akanbi ní Ààrẹ Buhari nìkan ni adarí tó jẹ́ olóòótọ́ tó gbógunti ìwà àjẹbánu ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà láti ìgbà tí Nàìjíríà ti wà.

"Mi ò mọ̀ wí pé mo le rí ọkọ̀ ojú irin ìgbàlódé àti ṣíṣe àtúnṣe òpópónà Eko sí Ibadan. Mi ò le gbàgbé Ààrẹ Buhari".

Oluwo ti Iwo bu ẹnu àtẹ́ lu àwọn ìjọba tó ti kọjá fún bí àwọn ohun améyérọrùn ṣe di ní orílẹ̀ èdè yìí, bí ó ṣe ní kò sí ìjọba tó tíì ṣe tó Ààrẹ Buhari lórí mímú ìlọsíwájú àti ìdàgbàsókè bá Nàìjíríà.

Oluwo fi kun pé gbogbo àwọn ọ̀nà tó so àwọn ìpínlẹ̀ ma ara wọn tó ti jẹ́ pípatì láti ọjọ́ pípẹ́ ni Ààrẹ ti parí.

Kini Oluwo tun sọ?

Bákan náà ló ṣàlàyé pe láti ìgbà tí ọ̀nà márosẹ̀ Eko sí Ibadan ti gba ẹ̀mí bàbá òun àti àwọn ohun tí òun máa ń rí ní ilẹ̀ òkèrè ló máa ń wu òun láti ní olórí tí yóò mú ìdàgbàsókè bá àwọn ohun améyérọrùn.

Nínú àtẹ̀jáde kan látọwọ́ alukoro rẹ̀, Alli Ibraheem, Oluwo ní "fún ìgbà àkọ́kọ́ láti bí ogún ọdún sẹ́yìn, èèyàn le wakọ̀ láàárìn Eko sí Ibadan láìpé wákàtí kan, láìsí súnkẹrẹ fàkẹrẹ ọkọ̀".

Oluwo ni: "Olóòótọ̀ ènìyàn nikan ló le ṣe èyí láì ní rí ìdíwọ́ àwọn alágbára tó ń jẹun ibẹ̀.

"Mo fẹ́ kí àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà máa sọ nípa dáadáa àwọn olórí wa, kó má jẹ̀ẹ́ aburú wọn nìkan wọ́n má sọ."

Bẹ́ẹ̀ náà ló rọ àwọn olórí mìíràn láti máa wo àwòkọ́ṣe Ààrẹ Buhari, bó ṣe pé fún àtìlẹyìn ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà fún ìjọba.