You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Covid-19 Quarantine: Kí ní ohùn tó sún àwọn ará ìlú kàn máa ṣé pàṣípààrọ̀ oúnjẹ pẹ̀lú fóónù?
Awọn olugbe ilu Xi'an lorileede China ti bẹrẹ si ni se pasiparọ ounjẹ laarin ara wọn.
Eyi ko si sẹyin ọwọn gogo ounjẹ ti wọn n koju nibẹ nitori isede ti ijọba gbe kalẹ.
Kaakiri oju opo ayelujara lawọn ara agbegbe naa ti n salabapin aworan orisi bawọn eeyan se n fi nkan ini wọn se pasiparọ ounjẹ.Koda wọn fi awọn nkan ẹrọ igbalode fi se pasiparọ ounjẹ.
- Lẹ́yìn wákàtí mẹ́ta tí wọ́n kéde pé ìyá mi kú, ó tún mi ọwọ́ rẹ̀ ooo - Ọmọ Iyabo Oko
- Ìjọba ìpínlẹ̀ Èkó ti wẹ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ márùn-ún àti òṣìṣẹ́ márùn-ún ilé ẹ̀kọ́ Dowen College mọ́
- Ta ni Oloye Lekan Balogun tí àwọn Ìgbìmọ̀ Afọbajẹ Ibadan fẹnukò pé òun ni Olubadan ilẹ̀ Ibadan kàn?
- Afenifere, PDP, Ohaneze sọ̀kò ọ̀rọ̀ sí Buhari lórí ọ̀rọ̀ tó sọ nípa ètò ààbò
- Àrà mérìírí! Ìbejí tí a bí ní ọdun 2021 àti 2022 pẹ̀lú ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀dògún láàrin wọn
Nkan bi eeyan miliọnu mẹtala lo ti deju mọle lati nkan bi ọjọ Kẹtalelogun osu Kejila ti wọn ko si ribi jade lati lọ fi ra ounjẹ.
Lẹnu ọjọ mẹta yi, pupọ awọn eeyan wọn yi lo n fitara han loju opo ayelujara.
Awọn alasẹ n pese ounjẹ fawọn ara agbegbe yi sugbọn awọn kan ni ounjẹ naa ki tọjọ tabi pe awọn ko tiẹ ri gba rara.
Loju opo Weibo,a ri fidio ati aworani nibi ti awọn eeyan n fi siga gba kabeeji,ọsẹ ifọ abọ lati fi parọ appu,tawọn mii si n fi paadi nkan osu obinrin se pasiparọ ewebẹ.
Ọkan ninu awọn fidio yi safihan olugbe kan to n fi ẹrọ idaraya Nintendo fi parọ indomie ati puff puff.
Olugbe kan sọ fun ileesẹ rẹdio Free Asia pe "awọn eeyan ti wọn jijọ n gbe inu ile kan naa n fi nkan se pasiparọ nitori wọn ko ni ounjẹ ti wọn yoo jẹ mọ''.
- Ìjọba Nàìjíríà kéde àwọn agbébọn gẹ́gẹ́ bíi agbésùnmọ̀mí káàkiri Nàìjíríà
- Àwọn akẹgbẹ́ Gómìnà Sanwo-Olu f'ohùn sílẹ̀ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ ìdójútini tó ṣẹlẹ̀ sí i lọ́wọ́ ọlọ́pàá ní Magodo
- Sanwo-Olu ṣèlérí láti ṣiṣẹ́ lórí àbọ̀ ìgbìmọ̀ olùwádìí ilé alájà 21 tó wó ní Ikoyi
- Ìgbìmọ̀ Afọbajẹ ilú Ìbàdàn buwọ́lu Lékan Balógun gẹ́gẹ́ bí Olúbàdàn tuntun ṣùgbọ́n....
- Adigunjalè kọlu Kemi Afolabi, wọ́n fi àdá ṣá òun àti awakọ̀ rẹ̀
- Àwọn òṣìṣẹ́ RUGIPO ti bẹ̀rẹ̀ ìyanṣẹ́lódì àìlópin
Ileesẹ iroyin yi tun sọ pe arakunrin kan fẹ fi foonu rẹ ati ẹrọ taabu gba irẹsi .
Wọn ni nkan ti n pada si tọjọ atijọ to se pe pasiparọ lawọn eeyan fi n seto karakata.
Ilu taa n pe ni Xi'an yi lo wa loju ina ajakalẹ arun Covid-19 yi tawọn alasẹ si ti gbe ilana kalẹ eyi tawọn eeyan bẹnu atẹ lu loju opo ayelujara.
Ọkan lara awọn ilana ati igbesẹ ijọba yi ni iru ọkan to sẹlẹ sawọn olugbe Mingde 8 Yingli tawọn alasẹ sadede sọ fun loruganjọ pe ki wọn kuro lọ si ibudo iyasọtọ.
Ajakalẹ yi jẹ eleyi to buru ju ni China lẹnu osu meloo kan sẹyin ti China n gbero lati mu ajakalẹ yi dopin.
Ireti ijọba China ni pe awọn yoo ribi mu dopin ki ọdun osupa oju ọrun wọn to waye ati saaju idije Olympics to yẹ ko waye ni Beijing losu to n bọ.