Ban on charcoal: Ìpínlẹ̀ Nasarawa fòfin de lílò èédú bí gáàsì ìdáná ṣe gbówó lórí

Kaka ki ewe agbọn dẹ, niṣe lo n le koko si.

Nibi t'awọn eeyan ti n pariwo pe afẹfẹ gaasi idana gbowo, ijọba ipinlẹ Nasarawa ti fòfin de lilo tabi tita eedu nipinlẹ naa.

Akọwe agba ileeṣẹ ijọba to n ri si ọrọ ayika ati alumọọni ilẹ, Aliyu Agwai lo fọrọ yii lede fawọn akọroyin niluu Lafia.

Ọgbẹni Agwai ni ọna ti wọn n ṣe eedu n ṣakoba fun ayika ati pe o n ṣe ipalara fun oju ọjọ, o si tun n jẹ ki ilẹ gbona.

Agwai awọn ohun ti o n jade nigba ti wọn ba n sun eedu lewu pupọ fun eeyan.

Agwai ṣalaye pe "gige igi inu igbo lulẹ yoo ṣakoba fun ibugbe awọn ẹranko inu igbo ati oju ọjọ.

Kò sí ẹranko to maa ruu la pẹlu t'awọn eeyan ba tẹsiwaju lati maa ge igi inu igbo lulẹ nitori ibugbe wọn ni wọn n bajẹ.

Nitori naa, gbogbo awọn to n ta tabi lo eedu ni lati dẹkun rẹ, bi bẹẹ kọ, wọn foju ba ile ẹjọ."

Akọwe agba ileeṣẹ ijọba to n ri si ọrọ ayika ati alumọọni lu awọn eeyan ipinlẹ Nasarawa lọgọ ẹnu lori bi wọn n ṣe fọwọsowọpọ pẹlu ijọba lori eto ilaniloyẹ.

Ẹwẹ, eeyan mejilelogon lo ti foju ba ile ẹjọ lori ẹsun titapa s'ofin imọtoto ayika.

Olupẹjọ, Abubakar Mohammed sọ fun ile ẹjọ pe awọn eeyan naa n ṣiṣẹ nigba ti eto gbale n gbata n lọ lọwọ.

O rọ ile ẹjọ lati fi wọn jofin ki o le jẹ arifikọgbọn fawọn eeyan mii.

Lẹyin naa ni adajọ Abdullahi Lande dajọ ẹwọn oṣu mẹfa mẹfa fawọn eeyan ọhun tabi ki wọn san ẹgbẹrun marun un si aadọta ẹgbẹrun owo itanran.