You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Sanwo-Olu kéde òfin tuntun nítorí ẹ̀dà Covid-19 tuntun, Omicron
Ijọba ipinlẹ Eko ti kede ofin tuntun to rọ mọ ajakalẹ arun Covid-19 nitori ẹda arun naa tuntun, Omicron.
Sanwo-Olu lo kede awọn ofin tuntun ọhun ninu atẹjade to fi sita loju opo Facebook.
Awọn ofin naa ko fi bẹẹ yatọ si awọn to ti wa nilẹ tẹlẹ, paapaa fun awọn to n bọ lati oke okun si Naijiria.
- Àwọn agbébọn dáná sun èrò ọkọ̀ 42 láàyè ní ìpínlẹ̀ Sokoto
- Ikú Sylvester Oromoni: Wo kókó òfin ìpínlẹ̀ Eko mẹ́wàá tó tako ẹgbẹ́ òkùnkùn
- Omicron: Kíni ìdí tí Nàìjíríà ṣe wà lára àwọn orílẹ̀-èdè tó léwu láti rírínàjò lágbàyé?
- Wolii Sotitobire jáde lọ́gbà ẹ̀wọ̀n!
- Ramon Adedoyin t'ọ́lọ́pàá mú nítorí ikú Timothy Adegoke gba ilé ẹjọ́ lọ, ohun tílé ẹjọ́ sọ rèé...
Ofin to rọ mọ ayẹyẹ ṣiṣe
- To ba ṣeeṣe, ki ayẹyẹ naa waye ni ita gbangba
- Iye awọn eeyan ti yoo peju sibi ayẹyẹ naa ko gbọdọ ju ida ọgọta iye eeyan to yẹ ko wa nibẹ lọ
- Gbogbo awọn ti yoo peju sibi ayẹyẹ ọhun gbọdọ pese ẹri pe awọn ti gba abẹrẹ ajẹsara Covid-19
- Ẹni ti ko ba tii gba abẹrẹ Covid-19 tẹlẹ gbọdọ pese ẹri pe awọn ti ṣe ayẹwo arun naa laarin wakati mejilelaadọrin.
- Gbogbo awọn ti yoo peju sibi ayẹyẹ ọhun gbọdọ ṣe ayẹwo Covid-19 tuntun, iyẹn "Antigen," ni gbọgan ayẹyẹ ọhun, yala wọn ti gbaabẹrẹ ajẹsara tẹlẹ tabi wọn ko tii gba
- Gbogbo awọn ti ara wọn ba gbona ju iwọn 37.5 gbọdọ pada sile wọn
- Gbogbo eeyan to wa nibẹ gbọgọ wọ ibomu
- Gbogbo eeyan gbọdọ fọ ọwọ wọn tabi lo sanitaisa ki wọn to wọle.
- Sanitaisa gbọdọ wa ni ẹnu abawọle gbọgan naa
- Awọn ti ọrọ yii kan ni ẹni ọdun mejidinlogun soke
Awọn arinrinajo lati ilẹ okeere
- Awọn arinrinajo gbọdọ ṣe ayẹwo Covid-19 ni wakati mejidinlaadọta ki wọn to wọ Naijiria
- Wọn gbọdọ ṣe ayẹwo Covid-19 laarin ọjọ meji ti wọn ba wọ Naijiria
- Gbogbo awọn ti wọn ko ba tii gba abẹrẹ ajẹsara wọn pe gbọdọ wa ni igbele ọlọjọ meje, wọn si gbọdọ ṣe ayẹwo Covid-19 ni ọjọ keje ọhun
Ni ti awọn to n lo ayederu kaadi abẹrẹ ajẹsara
Sanwo-Olu ni gbogbo awọn ti ọwọ ba tẹ pe wọn n lo ayederu kaadi pe awọn ti gbabẹrẹ ajẹsara Covid-19 yoo foju wina ofin.
O ni awọn ile ẹjọ pajawiri ipinlẹ Eko yoo ṣe ẹjọ gbogbo awọn ti aje ọrọ naa ba ṣi mọ lori.