Judicial Strike: Ẹ wo bí ẹgbẹ́ àwọn òṣìṣẹ́ amòfi ṣe gbé ilé ẹjọ́ ti pa ní Eko, Ondo

Ile ẹjọ giga Eko

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Ẹgbẹ àwọn oṣiṣẹ amofin ni Naijiria, JUSUN ti ya wọ ile ẹjọ giga ni Naijiria to wa ni ilu Eko wọn si ti ti i pa.

Bakan naa ni iroyin sọ pe ṣe ni wọ́n le awọn oṣiṣẹ to wa ninu awọn ile ẹjọ ati ninu ọgba jade sita ni nkan bii ago mẹsan owurọ ọjọ Iṣẹgun.

A gbọ pe ṣe ni ẹgbẹ JUSUN n fi dandan mu awọn akẹgbẹ wọn ninu iṣẹ ofin lati darapọ mọ iyanṣẹlodi wọn eyi to bẹrẹ lati ọjọ Iṣẹgun ọjọ kẹfa.

Bakan naa ni wọn ti awọn ọfiisi kọọkan ti wọn si lẹ iwe mọ ẹnu ọna wọn lati kede pe iyanṣẹlodi n lọ lọwọ.

Àkọlé fídíò, Àwọn èdè abẹ́ ahọ́n tóo lè fi sọ̀rọ̀ rèé láì tú àṣírí ọ̀rọ̀ rẹ áyé

Lati Ọjọbọ ọsẹ to kọja ni ẹgbẹ JUSUN ti kéde pe awọn yoo gun le iyanṣẹlodi lori ohun ti wọn n ja fun nipa didaduro eto isuna fun ẹka idajọ.

Ninu oṣu kẹta, ẹgbẹ naa ti ṣe ipade niluu Abuja ti wọn si fun ijọba ni gbedeke ọjọ mọkanlelogun. Bakan naa wọn ti kọ iwe jade yika gbogbo ileeṣẹ wọn lọjọ kini oṣu yii pe ki gbogbo wọn ti awọn ile ẹjọ pa jakejado orilẹede Naijiria ni ọjọ kẹfa oṣu kẹrin.

Ko pẹ ti eleyii waye ni iroyin tun wa lati ipinlẹ Ondo pe wọn ti ti awọn ile ẹjọ pa nibẹ nitori iyanṣẹlodi kan naa eyi to jẹ aṣẹ latoke wa.

Ọpọlọpọ oṣiṣẹ lo lọ sibi iṣẹ lọ Iṣẹgun ṣugbọn ti awọn aṣoju ẹgbẹ JUSUN lọ le wọn jade.

Awọn ibi ti wọn de ni Ile ẹj giga ipinlẹ naa, ile ẹjọ kotẹmilọrun, Majisireeti ati ile ẹjọ katakara.

Ẹwẹ, aarẹ orilẹede Naijiria fọwọ si abadofin kan lọjọ kejilelogun oṣu karun ọdun 2020 eyi to wa fun didaduro eto isuna ẹka idajọ jakejado Naijiria.

Bakan naa ni wọn si paṣẹ ki oluṣiro owo agba Naijiria yọ ninu owo naa latilẹ lara owo ti wọn n fun ipinlẹ loṣooṣu iyẹn fun awn ipinlẹ to ba kọ lati gba idaduro eto isuna yii laaye.

Ko tan silẹ Yoruba nikan, ni olu ilu orilẹede yii tii ṣe ilu Abuja, ṣe ni ẹgbẹ JUSUN lọ si ile ẹjọ giga lati gbe ẹnu ibode rẹ tipa ki awn oṣiṣ kankan ma lee wọle.

Bẹẹ naa lo ri ni ipinlẹ Rivers ti wọn ti ni awọn n gun le iyanṣlodi pe ki ijọba jẹ ki ẹka idajọ da duro.

Ile ẹjọ giga Rivers