Akomolede BBC Yoruba: Ìtúmọ̀ Àkànlò èdè àti ìwúlò rẹ̀ lóde òní
Akanlo ede kii ṣe ede ti ẹni ti ko gbọ Yoruba le maa gapa pe oun gbọ. Torinaa, ọna kan gboogi ti ọmọ Yoruba le fi ba ara wọn sọ̀rọ̀ ti ẹni to gbọ ta ta ta ko ni le gbọ rara ni lilo Akanlo Ede.
Arabinrin Sefunmi Victoria Atere to jẹ olukọ wa tonii ṣalaye pe a lee pe Akanlo Ede ni aṣiri tori a maa n lo lati fi aṣiri ohun ta n sọ pamọ fun ẹni to ba n gbọ ọ paapaa awọn elede miiran.
Ni ọpọ igba itumọ to yatọ ni akanlo ede maa n fun awọn ti ko gbọ Yoruba ni itumọ ọtọ ti ko tilẹ jọ mọ itumọ rẹ to fara sin rara.

Kilaasi alarinrin ni tonii gẹgẹ bi olukọ wa ṣe ṣalaye awọn apẹẹrẹ akanlo ede kọọkan ninu ede Yoruba.

