You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Seyi Makinde: Wo ìlànà tí ìpínlẹ̀ Oyo yóò gbà fi pín abẹ́rẹ́ àjẹ́sára Covid-19 tó gbà
Kọmisanna eto ilera nipinlẹ Oyo, Dokita Bashir Bello ti sọ pe awọn oṣiṣẹ eto ilera ipinlẹ naa ti wa si ipinlẹ Eko, lati gba abẹrẹ ajẹsara Covid-19 ti wọn.
Nigba to n ba BBC sọrọ, Dokita Bello sọ pe ajọ to n mojuto eto ilera alabọde ni yoo mojuto lilo rẹ.
Ati pe idanilẹkọ yoo bẹrẹ lonii fun awọn eeyan tuntun ti yoo fun awọn eniyan ni abẹrẹ ajẹsara naa, nitori pe o yatọ si awọn abẹrẹ ajẹsara to ku.
O ṣalaye pe awọn eleto ilera ni yoo kọkọ gba a , lẹyin naa ni yoo kan awọn olori ilu, lẹyin naa ni yoo kan awọn ti ọjọ ori wọn ti le ni ọgọta ọdun.
O ni ipele ti yoo tun tẹle wọn ni awọn to wa ninu ewu.
Ọsẹ to kọja ni abẹrẹ ajẹsara ti AstraZeneca de si orilẹ-ede Naijiria.
Aarẹ Muhammadu Buhari ati igbakeji rẹ, Yemi Osinbajo si ti gba lara rẹ ni opin ọsẹ to kọja.
- Ẹ wo àwòrán ìwọ́de àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ káàkiri Nàìjíríà lórí ọrọ owó oṣù tó kéré jùlọ
- Wo iye obìnrin lágbàáye tó ń kojú ìwà ipá, àti ohun tó ń ṣokùnfà ẹ̀?
- Ewú ńbẹ! Ẹgbẹ̀ àwọn oṣìṣẹ́ NLC faraya, yóò gùnlé ìyànṣẹ́lòdí lónìí
- Wo nkan tó yẹ kí o mọ̀ nípa Iskilu Wakili, afurasí Balógun Fulani tí OPC mú ní Ayetẹ ìpínlẹ̀ Ọyọ
- Wo àwọn ìpínlẹ̀ Yorùbá tó ti gba abẹ́rẹ́ àjẹsára Covid-19 ní Nàìjíríà