Sasa market crisis: Ìjọba àpapọ̀ kó nkan ìdẹ̀rùn fún àwọn tó kàgbákò nínú rògbòdìyàn ọjà Sasa

Ijọba apapọ Naijiria ti fi awọn nkan amayedẹrun ranṣẹ si awọn eeyan to padaanu dukia wọn lasiko rogbodiyan to waye ni Shasha nilu Ibadan.

Minisita to wa fun amojuto ajalu, itọju ọmọniyan ati idagbasoke awujọ, Sadiya Umar Farouq, lo ko awọn nkan naa fun ijọba ipinlẹ Oyo lorukọ ijọba apapọ.

Ileeṣẹ ijọba ti minisita naa n dari fi ikede naa sita lori ayelujara Twitter rẹ.

Ileeṣẹ iroyin abẹle, Voice of Nigeria sọ pe idile 928 ati eeyan 5,568 to ti di alainilelori ni agbegbe Sabo, Ojoo ati Akinyele nijọba ibilẹ Akinyele.

Lara awọn nkan ti wọn ko fun ijọba ipinlẹ Oyo ni apo irẹsi ati gari ẹẹdẹgbẹrun le mejidinlọgbọn (o ni kilogiraamu mẹwaa).

O ni iye kan naa fun apo ẹwa (o ni kilogiraamu mẹẹdọgbọn), kẹẹgi ororo (o ni lita ogun) mẹrindinlaadọta.

Awọn nkan mii to tun wa nibẹ ni apo iyọ mẹrindinlaadọta (oni kilogiramu ogun), apo pelebe isebẹ onihoro marundinlọgọjọ, ati paali tomato alagolo mọkanlelaadọrin.

Oṣu Keji ni ija ẹlẹyamẹya naa waye.