Privatization: Ààfàní ńlá ni yóò jẹ́ fún gbogbo ọmọ Naijiria tí ìjọba bá ta àwọn iléeṣẹ́ tó ti dẹnukọlẹ̀ - Atiku

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Igbakeji Aarẹ Naijiria tẹlẹ, Atiku Abubakar ti gboriyin fun ijọba apapọ lori igbesẹ rẹ lati bẹrẹ si n ta awọn ileeṣẹ ati ohun ini Naijiria kọọkan fun awọn aladani.

Atiku lo sọrọ naa ninu atẹjade kan to fi soju opo Twitter rẹ lọjọ Aiku.

O ni o pẹ ti oun ti n lọgun igbeṣe yii ṣugbọn wọn kọti ikun si oun.

Gẹgẹ bo ṣe sọ. "O ti le lọdun mẹwaa ti mo ti n lọgun pe ki wọn ta awọn ileeṣẹ ati ohun ini ijọba kan to ti dẹnukọlẹ ki wọn le ṣiṣe bo ṣe yẹ, paapaa ni ẹka ti epo rọbi."

O fi kun pe anfani nla ni yoo jẹ fun gbogbo ọmọ naijiria ti ijọba ba ta awọn ileeṣẹ rẹ kan to ti ko mu owo wọle, ti ko si ṣe anfani fun awọn eeyan ilu mọ.

Atiku ṣalaye pe, bo tilẹ jẹ pe ijọba Naijiria labẹ akoso ẹgbẹ oṣelu APC kọ lati tẹti si oun lasiko kan, ṣugbọn inu oun dun pe awọn naa ti ri ọgbọn ninu amọran oun.

Igbakeji Aarẹ tẹlẹri naa sọ siwaju si pe kii ṣe fun anafani ara oun ni oun ṣe ni ki ijọba ta awọn dukia ọhun.

Atiku pari ọrọ rẹ pe ko si ohun miran ti oun n fẹ ju pe ki Naijiria tẹsiwaju, ki awọn eeya rẹ si maa gbadun awọn ọrọ aje rẹ.