AGF Abdulrasaq Abdulganiyu, Bàbá gómìnà Abdulrahman Abdulrazaq tí ìpínlẹ̀ Kwara ti dágbéré fáyé l'Abuja

Owurọ oni, ọjọ Abamẹta ni baba to bi gomina ipinẹ Kwara, Abdulrahman Abdurasaq, jade laye.

Ọṣu Kọkanla, ọdun 1927 ni wọn bi baba naa, Abdulganiyu Abdulrasaq to ku si Ilu Abuja lẹni ọdun mẹtalelaadọrun.

Ilu Onitsha, nipinlẹ Anambra ni wọn bi baba naa si lọdun 1927.

Itan sọ pe o jẹ ọkan lara awọn akẹkọọ ipinlẹ ni Fasiti ilu Ibadan lọdun 1948, nibi to ti kẹkọ imọ ofin.

O di agbẹjọro agba (SAN) lọdun 1985.

Wo awọn nkan mii to gbe ile aye ṣe ki ọlọjọ to de

Nigba aye rẹ, o ti fi igba kan jẹ aṣoju orilẹ-ede Naijiria si orilẹ-ede Cote d'Ivoire laarin ọdun 1962 si ọdun 1964.

O jẹ ọkan lara igbimọ alakoso Naijiria lọdun 1964 si 1966, gẹgẹ bi Minisita fun Eto irinna.

Lẹyin naa lo jẹ kọmiṣọnna eto ẹnawo akọkọ fun ipinlẹ Kwara, nigba ti ijọba Yakubu Gowon da ipinlẹ naa silẹ l'ọdun 1967.

O tun jẹ kọmiṣọnna fun eto ilera, ati igbaye-gbadun ara ilu.

O tun jẹ Alaga igbimọ to n risi eto igbaniwọle awọn akẹkọọ sile ẹkọ imọ ofin Nigeria, Nigeria Body of Benchers.

Ko tan sibẹ o, baba naa ni iroyin tun sọ pe o jẹ agbẹjọro akọkọ lati iha Ariwa Naijiria.

O tun jẹ Aarẹ ileeṣẹ to n mojuto paṣipaarọ ipin idokowo Naijiria laarin ọdun 2000 si 2003, ati igbakeji aarẹ ileeṣẹ naa laarin ọdun 1983 si 2000.

Ẹwẹ, o jẹ oye Mutawali ilu Ilorin, Tafida ilu Zazzau nipinlẹ Kaduna.

Iyawo rẹ to jẹ ẹni aadọrun ọdun, Raliat AbdulRasaq, ati ọmọ ati ọmọ-ọmọ lo fi silẹ saye lọ.