LASTMA: A ṣèlèrí láti fi òṣìṣẹ́ yìí jófin tó bá ṣẹ̀

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ajọ to n mojuto igbokegbodo ọkọ loju popo nipinlẹ Eko, LASTMA, ti fesi lori fidio kan to jade sori ayelujara laipẹ yii, ninu eyi ti oṣiṣ rẹ kan ti n ka owo 'to gba lọwọ awakọ kan' to tapa si ofin iriina.

Ọkunrin kan, Ọgbẹni Ibukun Mike lo fi fidio bi awọn oṣiṣẹ ajọ naa ṣe gba owo lọwọ rẹ ati awọn awakọ miran, nitori pe wọn ṣẹ si ofin.

Ọgbẹni Ibukun ṣalaye pe ọrọ naa ṣẹlẹ ni ọjọ kẹẹdogun, oṣu Karun, ọdun 2020.

O gba pe lootọ, oun atawọn awakọ mii loju popo ru ofin irinna nipa gbigba ọna ti ko tọ ọ, ṣugbọn o ni wọn ṣe bẹ ẹ nitori pe abala na ti wọn n gba tẹlẹ di pa fun sunkẹrẹ-fakẹrẹ ọkọ.

O ni oṣiṣẹ LASTMA kan lati ọfiisi wọn to wa ni agbegbe Masa-Masa da wọn duro, o si ko wọn lọ si ọfiisi wọn nibi to ti jade lọ ṣugbọn o sọ fun igbakeji rẹ ko gba ẹgbẹrun lọna aadọta lọwọ onikaluku wọn lai fun wọn ni iwe ẹri pe wọn sanwo.

Ajọ LASTMA ni awọn yoo ṣewadii iwa ti awọn oṣiṣẹ wọn hu yii, awọn yoo si fi ẹni ti igba ọrọ naa ba ṣi mọ lori jofin.

"A ti ri fidio kan to tan kalẹ lori ayelujara nipa pe awọn oṣiṣẹ wa kan n gba owo ẹyin lọwọ awọn awakọ. Ajọ LASTMA ti ri i, a si ti bẹrẹ iwadii. Oṣiṣẹ tọwọ ba tẹ yoo jiya iṣẹ ọwọ rẹ".

Bo ṣe yẹ ko jẹ gangan ni wipe ẹnikẹni to ba ru ofin irina gbudọ san faini si asuwọn ijọba ki wọn si gba iwe 'mo sanwo' ṣugbọn Ibukun ni wọn kan gba owo lọwọ awọn ni lai si akọsilẹ.

Ninu fidio ti Ibukun fi soju opo Instagram to gan an mọ orukọ ajọ LASTMA ati gomina Sanwo-Olu lori ayelujara.

Eyi lo fa oju ajọ LASTMA si fidio naa ti wọn si ni awọn yoo ṣewadii lati mọ aridaju ki wọn fi ọwọ ofin mu oṣiṣẹ to ba ṣẹ.

Bakan naa wọn fi si oju opo Twitter wọn pe ki awọn eeyan ma kọ lati fi ẹjọ oṣiṣẹ LASTMA ti wọn ba ri to n ṣe aṣemaṣe sun awọn.