You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Boko Haram n fipá bá mi lòpò ní òpò ìgbà léyìn tí wọn kọlu ìlú wa- Omọbinrin náà
Mi o le fori jin ibatan mi ọmọ iko Boko haram to fipa bamilopọ
Loni, ọjọ Kejidinlogun, oṣu Kẹfa, ti se ayajọ ti ajọ iṣọkan agbaye la kalẹ lati mu opin ba iwa ifipabanilopo lasiko ikọlu,
Odomobirin kan ni Naijiria to ni ki BBC forukọ bo oun laṣiri sọrọ lori bi ibatan oun kan to jẹ ọmọ ikọ Boko Haram ati awọn miran ti ṣe fipa ba oun ati awọn ọmọbinrin miran lopọ f'un igba pipẹ ni ariwa Naijiria.
- Yẹ̀kínì kan kò lè yẹ ipinnu wa láti ṣí iléèwé pàda lóṣù yí - ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo
- Ann Grace Aguti, Obìnrin kan to fẹ́ ọkọ mẹ́ta lẹ́ẹkàn ṣoṣo
- Ìlànà ìjìnàsíraẹni 'social distancing' forí ṣánpọ́n bí ìrun Jímọ̀ ṣe bẹ̀rẹ̀ padà ni Ilorin
- Yẹ̀kínì kan kò lè yẹ ipinnu wa láti ṣí iléèwé pàda lóṣù yí - ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo
Arabinrin yi ni iṣẹlẹ aburu yi ṣẹlẹ sí òun lẹyin ti awọn ọmọ ikọ boko haram ṣigun bo ilu wọn.
O ni: Won fipa ba mi lopọ, wọn si fi mi fun awọn ọmọ ikọ boko haram gẹgẹ bi iyawo
Bi Boko Haram ti ṣe wọ ilu wa, wọn pa gbogbo awọn ọkunrin ilu wa sọna si awọn ile wọn si ko gbogbo awa obinrin lọ"
"Ni ọjọ yi ni ibatan mi to jẹ Boko Haram wa sọ fún mi pe lati oni lọ, mo ti di iyawo ohun,dukia ohun .Lọjọ naa lo si ti bẹrẹ si ni fipa bamilopọ"
"Leyin igba diẹ ti ede aiyede waye laarin oun ati awọn ọmọ ẹgbẹ naa miran ti won si pa a, wọn fi mí fun ẹlomiran gẹgẹ bi iyawo."
Arabinrin ti a n wi yi sọ pe oun ati awọn ọmọbìnrin mii ribi sa mọ wọn lọwọ nibi ti awọn oniṣẹ ibi yii ko wọn pamọ si lasiko ti wọn n sun ni nkan bi aago kan oru.
O fi kun ọrọ rẹ pe tohun ti pe awon ribi sa asala kuro lọwọ awọn to mu awọn, oju buruku lawọn to ku ni aaye t'awọn atipo fori pamọ si to wa ni Bama ni Iwọ oorun ariwa Naijiria fi n wo awọn.
"Ibikibi ti a ba rin si, wọn a máa na ika aleebu sí wa pe iyawo Boko haram ni wa
Afi bi igba pe ebi wa ni bi wọn ti ṣe mu wa l'ẹru.
Ni temi, mi o ro pe mo le forijin awọn ọmọ ikọ Boko haram fun nkan ti wọn foju mi ri"
Kini Arabinrin yii fẹ di ni ọjọ iwaju rẹ?
Arabinrin yi to ti pada si Ile ẹkọ girama ni o wu oun lati di ọmọ ogun lọjọ iwaju ki oun ba a le dojú ija kọ awọn ọmọ ikọ Boko Haram.
"Erongba mi ni lati pari ẹkọ mi kì n si darapọ mọ awọn ọmọ ogun Naijiria, kí n wọ inu baalu kí n sì sọ ado oloro lu awọn olubi yi ki wọn si parẹ tan yanyan ni Naijiria"
Yatọ sí eto ẹkọ rẹ, o ni oun fẹ kọ iṣẹ ranṣọ ransọ laaye ikọsẹ to wa ní ibùdó awọn atipo.
O fikun un pe lati igba ti wọn ti ji oun gbe kò sì ọjọ kan toun kii sunkun titi ti awọn ikọ ẹlẹyinju aanu Al Amin wa saanu fun oun.
Ajọ iṣọkan agbaye UN ni awọn ya ọjọ Kọkandinlogun oṣu Kẹfa ọdọọdún sọtọ lati mu opin ba ifipabanilopo fawọn to wa ninu wahala ati laasigbo bi ti arabinrin yi.