World Press Freedom Day: Ọ̀pọ̀ ìgbà ni àwọn jàǹdùkú ká mi mọ́lé nítórí ìròyìn tí mo kà

Àkọlé fídíò, World Press Day: Ọ̀pọ̀ ìgbà ni àwọn jàǹdùkú ká mi mọ́lé nítórí ìròyìn tí mo kà

Oniroyin ni Folake Otuyelu jẹ, ni orilẹ-ede Naijiria. Gẹgẹ bi ọpọ akọroyin kaakiri agbaye, Folake ti dojukọ ipenija oriṣiriṣi lẹnu iṣẹ rẹ.

Idunkooko mọ ni lati ọdọ awọn oloṣelu, agba ilu, tabi janduku naa ko gbẹyin ninu awọn ipenija naa, paapa to ba ka iroyin ti iru awọn eniyan bẹ ẹ gba pe o tako wọn tabi tabuku wọn.

Ẹ gbọ iriri rẹ ni ẹkunrẹrẹ ninu fidio yii.