Coronavirus: 'Ewu ni tí Covid-19 bá wọ àdúgbò wa bí a ṣe fún pọ̀ yìí'

Àkọlé fídíò, Coronavirus: 'Ewu ni tí Covid-19 bá wọ àdúgbò wa bí a ṣe fún pọ̀ yìí'

Ọmọ maarun ni tọkọtaya bi, wọn si n gbe ninu yaara kan ṣoṣo ni agbegbe Kibera lorilẹ-ede Kenya.

Agbegbe yii jẹ ibi ti awọn to ku diẹ kaato fun lawujọ n gbe, oun naa si ni iru agbegbe naa to tobi julọ ni Kenya.

Ọpọlọpọ wọn lo n gbe ninu yaara kan pere, botiwu ki wọn o pọ to ninu idile kan.

Bakan naa ni o ṣeeṣe ki ọrọ ọwọ fifọ gẹgẹ bi ọkan lara ọna lati dena itankalẹ Covid-19 ko nira nibẹ nitori ọwọn gogo omi. Rira ni wọn n ra omi, ọpọ si ni ko tun lowo lọwọ lati ra omi naa.