You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Aso Rock: Àwọn adigunjàlè pa akọ̀wé àgbà Ilé Ààrẹ l’Abuja
Akọwe agba fun awọn oṣiṣẹ ni ile aarẹ Labuja, Jalai Arabi ti ni ibanujẹ ọkan lo jẹ fun oun pẹlu bi awọn adigunjale ṣe pa arabinrin Laetitia Naankang Dagan ninu ile rẹ.
Arabinrin Laetitia Naankang Dagan ki o to papoda ni igbakeji adari eto ni ile aare, Aso Rock in Abuja.
Arabi ṣe apejuwe iku obinrin naa gẹgẹbi oun to dun awọn olubaṣisẹ rẹ, awọn ẹbi ati ara rẹ ati gbogbo awọn oṣiṣẹ ile aarẹ de eegun.
Arabinrin Dagan to jẹ ọmọ ọdun mẹtadinlaadọta ṣiṣẹ ni ọfisi rẹ titi di aago mẹjọ, amọ ni aago mọ̀kanla ni awọn adigunjale wọ ile rẹ, ti wọn si pa a.
Gẹgẹ bi ọrọ Oludari agba naa, o mo arabinrin to papoda naa jẹ akinkanju ẹda, ti iku rẹ si jẹ eleyii to buru jai ni aipe ọjọ.
O ni oun ti awọn fi pa irọnu rẹ ni wi pe, o gbe igbe aye to wu eniyan, to si ṣiṣẹ fun orilẹede rẹ pẹlu gbogbo okun ati agbara rẹ.
Jalal to ni iwadii ti bẹrẹ lori iṣekupani naa, ati wi pe oun ni igbagbọ pe awọn ọlọpaa yoo ṣe iwadii awọn to wa ni idi iṣekupani naa.
Oludari agba fun awọn oṣiṣẹ ni ile aarẹ naa wa gbadura ki Olorun fi ọrun kẹ oloogbe naa, ki o si fi irọrun fun awọn ẹbi ati ara ti oloogbe naa fi silẹ.