National ID: Anthony Joshua gba nọ́mbà ìdánimọ̀ NIN, wo èsì àwọn ọmọ Nàìjíríà

Eto iforukọsilẹ fun nọmba idanimọ awọn ọmọ orilẹede yii ki ṣe eyi ti o ṣokunkun si ọpọ mọ bayii paapaa julọ lẹnu lọwọlọwọ yii.

Amọṣa gbigba rẹ lo di wahala nla sawọn ọmọ orilẹede Naijiria lọrun paapaa julọ ilana ati gba a.

Ni aṣalẹ ọjọ Iṣẹgun ni ajọ to n ṣe kokari eto iforukọsilẹ kaadi idanimọ lorilẹede Naijiria, NIMC kede loju opo Twitter rẹ pe gbajugbaja akanjẹ agbaye ni to jẹ ọmọ Naijiria ṣugbọn to n ja fun orilẹede Gẹẹsi pẹlu ti gba forukọsilẹ fun kaadi idanimọ gẹgẹ bi ọmọ Naijiria, o si ti gba nọmba idanimọ rẹ, NIN.

Pa-pa-pa ti eto naa lọ fun Anthony Joshua lo wu ariwo awọn ọmọ orilẹ€de Naijiria sita ti olukuluku si bẹrẹ si nii sọ ohun oju wọn ri lori ilana ati gba.

Bi awọn kan ṣe n faraya pe nitori pe Joshua lorukọ, o tete ri tirẹ gba, ṣugbọn ọpọ ni o ti wa lẹnu igbesẹ ati gba iwe idanimọ ati nọmba naa ṣugbọn ti ko si ohun to jade nibẹ.

Bakan naa ni awọn kan ṣalaye pe oniruuru aṣemaṣe bii jibiti ati riba gbigba lawọn ọmọ Naijiria n dojukọ labẹ eto naa.