Buhari: Èsì mi lórí orúkọ àwọn mínísítà

Buhari

Oríṣun àwòrán, Bayo Omoboriowo

Aarẹ Muhammadu Buhari ti ni bi o tilẹ jẹ pe awọn ọmọ Naijiria wa lọrun oun lati gbe orukọ awọn minisita jade, awọn t'oun mọ ni oun yoo yan.

Aarẹ sọ eleyi nibi ipade to ṣe pẹlu awọn adari ile igbimọ aṣofin lalẹ ọjọbọ.

Aarẹ ni ọpọ minisita t'oun yan ni saa kinni ijọba oun loun ko mọ denu tori ẹgbẹ oṣelu atawọn mii lo yan wọn fun oun.

Ṣugbọn ni bayii, "maa rii daju pe mo foju balẹ ki n le ri imu", eyi tumọ si pe awọn ti aarẹ mọ daadaa ni yoo yan lati ba a ṣiṣẹ.

"Awọn kan to wa sibi ipade naa tilẹ fẹ yọju wo orukọ naa ki wọn le lọ fẹdọ lori oronro sun ṣugbọn lakoko yii, mi o ni gba ki ẹnikẹni ti mi lati gbe orukọ jade".

Ọjọ ikọkandilọgbọn oṣu ikarun un ọdun 2019 ni aarẹ Buhari ṣe iburawọle ṣugbọn lati igba naa, ko tii yan awọn minisita rẹ.

Àkọlé fídíò, Okunrounmu: Ijọba Buhari jẹ ijiya Ọlọrun fun Naijiria

Lati igba naa si lawọn ọmọ Naijiria ti n reti reti koda lẹyin ti aarẹ ile igbimọ aṣofin agba gan, Ahmed Lawal kede pe yoo jade ki ọsẹ yii to kanlẹ.

Ẹwẹ nigba to de ibi ipade apejẹ alẹ ana, Lawal yi ẹnu pada o ni oun ko sọ bẹẹ lẹyin pe Sẹnetọ Bassey Akpan ti ipinlẹ Akwa Ibom mẹnu ba ọrọ idi to fi yẹ ki ijọba ti gbe e jade ki wọn to lọ fun isinmi ni oun, Ahmed fi da wọn loju pe o ṣeese ko jade lọsẹ yii gan.

Ẹwẹ, lẹyin ipade naa, aarẹ dupẹ lọwọ awọn ọmọ ile igbimọ aṣofin fun bi wọn ṣe n ṣe iṣẹ wọn ti wọn si n hu iwa ire.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: