You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Adam Johnson: Agbábọ́ọ́lù Sunderland nígbà kan rí jáde lẹ́wọ̀n lẹ́yin ọdún mẹ́ta
Baba agbabọọlu Sunderland ati Ilẹ Gẹẹsi nigba kan ri, Adam Johnson ni inu oun dun pe ọmọ oun ti jade lẹwọn
Johnson gba bọọlu fun Middlesbrough, Manchester City ati Sunderland ki wọn to ju u si ẹwọn ọdun mẹfa ni 2016 nitori wipe o ba ọmọ ọdun mẹẹdogun kan ṣere ifẹ.
Baba rẹ, Dave ba awọn akọroyin sọrọ ni iwaju ile ọmọ rẹ ẹni ọdun mọkanlelọgbọn ni Castle Eden, County Durham.
Johnson, to gba bọọlu fun ikọ England nigba mejila ni wọn da silẹ ni ẹwọn lẹyin to ti lo ilaji ẹwọn rẹ.
Ẹsun ti wọn fi kan an ni wipe o fẹ ba ọmọdebinrin naa ṣe ere ifẹ, to si fi ẹnu ko o ni ẹnu. Bi ẹjọ naa ṣe bẹrẹ ni ẹgbẹ agbabọọlu rẹ, Sunderland yọ ọwọ ninu iwe adehun bọọlu rẹ, eyi ti wọn ti n fun ni ẹgbẹrun lọna ọgọta pọun ni ọsẹ.