Ògidì ọmọ Yorùbá gbọ́dọ̀ mọ 'áayan ògbufọ̀' dáadàa!

Àkọlé fídíò, Ògidì ọmọ Yorùbá gbọ́dọ̀ mọ 'áayan ògbufọ̀' dáadàa

Èdè Yorùbá jẹ́ ọ̀kan lára àmì ìdánimọ̀ Yorùbá nitootọ.

BBC Yorùbá jáde lọ bèèrè ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ 'Philanthropist' lọ́wọ́ àwọn ògidì ọmọ 'káàrọ̀ oòjíire bí?' nígboro Eko.

Awọn eeyan sọju abẹ niko lori irufẹ ẹni ti oloyinbo n pè ni Philanthropist; ṣugbọn àwọn miran kò gbàá.

'Philanthropist' jẹ ọrọ apejuwe kan ni èdè oyinbo to tumọ si aláàánú, onínúure, olóore ẹ̀dá, olùrànnilọ́wọ́ fún aláìní ni èdè Yorùbá.

Irufẹ àwọn eeyan yii ni wọn n nu omije ọ̀pọ̀ nù ni oriṣiiriṣi ọna láì retí ohunkohunpada ni eyi ti idagbasoke fi n ba awujọ.

Ko nii fi ṣe boya o mọ wọn ri tabi o kò mọ wọn rí rara, Idi ni yii ti Yoruba fi maa n ni 'ajumọbi kò kan ti àánú, ẹni ti Ọlorun ba ran si ni lo n ṣe ni lóore'.

Igba gbogbo ni wọn fi maa n wa ilọsiwaju ọmọlakeji wọn ni awujọ lainaani ìran, ẹ̀yà tabi ẹ̀sìn ẹni ti wọn fi ṣaanu fun ni ọpọ igba.

Njẹ iwọ naa jẹ ẹlẹyinju aanu ni agbegbe rẹ?