Ogun Primary: Ogunbanjo ni yóò dupò gómìna f'ẹ́gbẹ́ ANN

Ademola Olalekan Ogunbanjo ni yoo dije fun ipo gomina nipinlẹ Ogun labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Alliance for New Nigeria, ANN ninu idibo ọdun 2019 .
Ọjọbọ, ọjọ kẹrin, osu kẹwaa ni ẹgbẹ ANN kede Ogunbanjo pe oun lo jawe olubori ninu idibo abẹle to waye nilu Abeokuta lẹyin ti awọn meji ti wọn fẹ jọ figagbaga tẹlẹ yẹba fun un.

Ọpọlọpọ awọn oludibo to jẹ ọmọ ẹgbẹ lọ jade wa yan ẹni to wu wọnlati ṣoju wọn ninu idibo 2019 sile igbimọ aṣofin ati gomina ni gbongan Centenary ni Ake nilu Abeokuta.
Awọn ọdọ lo pọ ninu ẹgbẹ ANN, inu ẹgbẹ yii kannaa ni illumọka agbaninimọran Fẹla Durutoye ti jawe olubori gẹgẹ bi ẹni ti yoo dupo Aarẹ orilẹede Naijiria labẹ asia ẹgbẹ ANN ninu idibo ọdun 2019.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Ẹgbẹ oṣelu ANN kede Durotoye gẹgẹ bi oludije fun ipo Aarẹ labẹ asia ẹgbẹ ọhun lọjọ kọkandinlọgbọn, osu kẹsan an to kọja.

Oríṣun àwòrán, Twitter/@feladurotoye
Diẹ lara awọn ti yoo dije fun ipo kan tabi omiran ninu ẹgbẹ ANN ninu idibo ọdun 2019 ni wọnyii.

Oríṣun àwòrán, ANN
Ẹ o ranti pe Durotoye ati ẹgbẹ ANN wa lara awọn ti o n ṣe ipolongo pe ki awọn ọdọ wa lara awọn to n ṣe ijọba orilẹ-ede Naijiria.














