Ọsun Election 2018: Ilé isẹ́ ọlọ́pàá ti bẹ̀rẹ̀ ìmúrasílẹ̀
Ajọ ọlọpaa ko gbẹyin nibi igbaradi fun idibo si ipo gomina ni ipinlẹ Osun ti yoo waye ni Ọjọ Satide, Ọjọ Kejilelogun, Osu Kẹsan an, ọdun 2018.
Awọn oludije lati ẹgbẹ oselu mejidinlaadọta ni wọn yoo figagbaga lasiko eto idibo naa.
Bakan naa, awọn alaabo fun ara ilu,Civil defense naa o gbẹyin ninu igbaradi fun idibo ti yoo waye lọla ode yii.
Eyi n waye gẹgẹbi ìgbáradì ilé isẹ́ ọlọ́pàá fún ètò ìdìbò sípò gomina tí yóò wáyé ní Satide.
Aago méjìlá ọjọ́ Ẹti ni ìséde yóò bẹ̀rẹ̀ ṣáájú ìdìbò náà
Ọjọ́ kejilelogun, oṣù kẹsan an (ọjọ Abamẹta to m bọ) ni ètò ìdìbò náà yóò wáyé.
Oga agba fún awọn ọlọpaa, Idris Ibrahim lo kede pe àwọn kọmiṣọna mẹjọ ati igbakeji kan ni wọn yoo ṣiṣẹ amojuto ìdìbò náà ti yoo fun àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ Ọṣun laaye lati dìbò yan ẹni tó wù wọn.

Oríṣun àwòrán, @npf
O ni ọkọ̀ ofurufu meji yoo ṣiṣẹ pẹlu ọgbọn ọkọ ayẹta ati ọọdunrun ọkọ ọlọpaa ti yoo maa lọ lati ibikan si ikeji ni wọn ti kó ranṣẹ ṣaaju idibo naa.
Àwọn agbofinro ti dé si ipinlẹ Ọṣun pẹlu àwọn ohun eelo ti wọn nilo lati pese eto aabo fawọn eniyan ipinlẹ Ọṣun lasiko idibo.
Gbogbo wọn yoo fọwọsọwọpọ pẹlu àwọn oṣiṣẹ eleto aabo to ku lati pese eto aabo to ye fawon olugbe ipinle Oṣun lasiko yii.
Awon ọtẹlẹmuyẹ CID aati IRT pẹlu FCIID naa ti de sipinlẹ Ọṣun bayii.
Idris kede pe agogo mejila oru ọjọ Ẹti, ọjọ kọkanlelogun, oṣu kẹsan an ni ìséde yoo bẹrẹ.
Idris fi awọn nọmba yii lede lati pe ti ẹnikẹni ba n huwa aitọ: (i) 08037025670 (ii) 08037160989 (iii) 08033415589 (iv) 08032451594.
O ni wọn kò ni faaye gba àwọn ti won maa n gberò láti da eto idibo rú rara.
NOMBAẸGBẸ OṢELUORUKỌ OLUDIJE ATI IGBAKEJI WỌN LABẸ
01AJulius Olapade Okunola - Azeez Kayode Jimoh
02AAOgunmodede Adeloye - Adepoju Timothy Adetunji
03ABPOludare Timothy Akinola - Halimat Bunmi Ibrahim
04ACDGbenga Afeni - Oni Esther Oluwatoyin
05ACPNRufai Adebisi Mujidat - Agboola Peter Oluremi
06ADJames Olugbenga Akintola - Abdulhakeem Oyeniyi Bello
07ADCFatai Akinade Akinbade - Arowolo Oladele
08ADPAdeoti Moshood Olalekan -Durotoye Adeolu Akinbola
09AGAKehinde Olufemi Lawrence - Lawal Oluseyi Afusat
10AGAPAdejola Adebayo Rufus - Adebayo Adewale Olaolu
11ANRPAlarape Babatunde A. - Adelu Ayoade David
12APAAdeleke Adesoji M.A - Agbonmagbe Tosin Omowumi
13APCAdegboyega Isiaka Oyetola - Benedict Olugboyega Alabi
14APGAOluwatoki Adetokunbo Adedayo A. - Adefila Mary Olaitan
15APPEkundayo Ademola Precious - Ojo Olugbenga Samuel
16BNPPOlapade Olajide Victor - Dunmade Adejoke Wuraola
17C4CIlori Titus Oluwafemi - Alabi Temitayo Kadijat
18DAMutiu Abiodun Ibrahim - Fafioye Hammed Abiodun
19DPCAderemi Aree - Onitayo Yemisi Mary
20DPPSolomon Ayodeji Oni - Issa Ademola Aderibigbe
21FIPBabatunde Salako Joseph - Onifade Saheed Alade
22GDPNAdetipe Adebodun Abiola - Ajiboye Funke
23GPNRafiu Shehu Anifowose - Oluwatoyin Adebayo
24HDPAdedoyin Adegoke Joshua Oluwole - Olawale Adesoye Adewumi
25KPFabiyi Oluseyi Olubunmi - Ibrahim Adekunle Akande
26LPBabatunde Olaniyi Loye - Aderonke Adebayor Jabar
27MMNRaphael A. Feranmi - Ariyo Sunday Sina
28MPNLawal Ganiyu Akanfe - Idowu Kayode Olusegun
29NCPKamarudeen Kalemi Abiodun - Lawal Temitope Serifat
30NPCOlaniyi Anthony Fadahunsi - Abdulrasheed Afusat Olanike
31NEPPJegede Hannah Taiwo - Rebecca Adeleke Oladepo
32NNPPAdefare Segun Adegoke - Adeyeye Nurudeen Adeyemi
33PANDELAdebayo Rasheedat - Ajibola Fatimat
34PDCKolawole Rafiu Ojonla - Oladapo Deborah Oluwatoyin
35PDPAdemola Nirudeen Adeleke - Albert A. Adeogun
36PPAAdedokun Musbau Olalekan - Ibrahim Bukola
37PPCIfeolu Kehinde Adewumi - Sunday Makinde Babawale
38PPNAkintunde Adesoji - Akanmu Saheed Abiodun
39PRPBadmus Tajudeen Adefola - Olajire Gbolahan
40PTAdegboyega Aderemi - Usman Omobolaji Taofeek
41RPAyodele Mercy Tosin - Adejumo Mukaila
42SDPIyiola Omisore - Lawal Azeez Olayemi
43SNPAyoade Ezekiel Adegboyega - Omolade Anike Adebayo
44SPNAlfred Adegoke - Lameed Gafar
45SPNAdediji Olanrewaju Adewuyi - Alabi Ola-Olu Adeniyi
46UPPOdutade Olagunju Adesanya - Karonwi Festus Olamilekan
47YDPAdebayo Adeolu Elisha - Aleem Atinuke
48YPPAdetunji Olubunmi Omotayo - Salawu Kareem Adeniyi
















